Saheed fi fisa lu Samson ni jibiti, ladajọ ba ni ko lọọ ṣe Falẹntain lẹwọn

Spread the love

Adajọ ile-ẹjọ Majisreeti kan niluu Oṣogbo ti paṣẹ pe ki wọn lọọ fi Saheed Ademọla pamọ sọgba ẹwọn titi di ọjọ kẹrinla, oṣu keji, ọdun yii, lori ẹsun ole-jija ti wọn fi kan an.

 

Saheed, ẹni ọdun mejilelogoji, ni wọn lo gba ẹgbẹrun lọna ojilelẹẹẹdẹgbẹrin Naira (#740,000), lọwọ Ọlapade Samson Taiwo pẹlu ileri pe oun yoo ba a ṣe fisa ilẹ-okeere fun awọn onibaara rẹ.

 

Gẹgẹ bi Inspẹkitọ Fagboyinbo Abiọdun ṣe ṣalaye fun kootu, inu oṣu kẹta, ọdun 2018, ni Saheed gba owo naa lọwọ Ọlapade lagbegbe Ogo-Oluwa, niluu Oṣogbo.

 

Ogoji eeyan ti wọn jẹ onibaara Ọlapade la gbọ pe wọn nilo iwe-irinna naa, Saheed si ṣeleri pe oun yoo ṣe iṣẹ naa laṣeyọri, ṣugbọn to pada ja si jibiti.

 

Fagboyinbo ni latigba ti olujẹjọ ti gba owo ọhun ni wọn ko ti gburoo rẹ mọ; ko ko iwe-irinna wa, bẹẹ ni ko da owo pada, nigba to si di pe awọn onibaara n yọ ọ lẹnu lo fori le agọ ọlọpaa lati fi ẹjọ Saheed sun.

 

Ẹsun mẹta ọtọọtọ ni wọn fi kan Saheed, lara wọn ni irọ pipa ati ole jija, o si sọ pe oun ko jẹbi rara nigba ti wọn ka awọn ẹsun naa si i leti.

 

Agbẹjọro olujẹjọ, Tunde Adedokun, ni ki ile-ẹjọ gba oun laaye lati gba beeli olujẹjọ, ki wọn si tun faaye beeli silẹ fun un lọna irọrun.

 

Ṣugbọn adajọ kootu ọhun, O.A. Ọlọyade, fọwọ rọ arọwa agbẹjọro olujẹjọ sẹyin, o si paṣẹ pe ki wọn lọọ fi olujẹjọ pamọ sọgba ẹwọn titi di ọjọ kẹrinla, oṣu yii, ti ṣe ayajọ ọjọ ololufẹ

 

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.