Ṣalewa gbe ọmọ sa kuro nile, o ni ‎baba ẹ fẹẹ fi i ṣoogun owo

Spread the love

Ile ẹjọ ibilẹ Ọja’ba to wa ni Mapo n’Ibadan ti fopin si ibaṣepọ lọkọlaya ọlọdun mẹfa to wa laarin Ọpẹyẹmi Alade ati Oyelọla Ṣalewa Alade nigba ti iyawo fẹsun kan ọkọ pe o fẹ fọmọ awọn ṣoogun owo.

 

Ṣalewa, ẹni to rọ ile ẹjọ lati tu igbeyawo pin oun atọkọ ẹ niya lỌjọbọ (Tọsidee) to kọja sọ pe nitori pe ọkunrin naa fẹẹ dolowo ojiji lo ṣe fẹẹ fi akọbi ọmọ awọn ṣetutu ọla to si purọ foun pe nṣe loun fẹẹ ro ọmọde naa lagbara.

 

Obinrin to pera ẹ loniṣowo yii ṣalaye pe “Ẹgbẹji lawọn Yoruba maa n pe loloogun ṣugbọn mi o le sọ ẹni to n ṣoogun ju ninu Ẹgbẹji ati ọkọ mi. Oriṣiriṣii ọṣẹ dudu ti mi o mọdi ẹ lo maa n gbe wale, bo ṣe n wẹṣẹ lọsan-an lo n wẹ wẹṣe loru.

 

“Gbẹrẹ to wa lara ẹ ko lonka, ko si orikerike ara ti ko sin gbẹrẹ si. Bi mo ba si ṣe waasu fun un pẹrẹ, ija lo maa sọ ọ da mọ mi lọwọ.”

 

“Ṣadeede lo wale losan-an gangan ọjọ kan to ni oun ni lati ṣe aajo kan fun akọbi wa to n jẹ Azeezat lati ro o lagbara.

 

“Ọkọ mi o ri alaye Kankan ṣe lori iru aajo agbara to fẹẹ ṣe fun ọmọ ti ko tii pe ọmọọdun mẹta ati idi to ṣe fẹẹ ro o lagbara. Idi niyẹn ti mo ṣe gbe ọmọ yẹn sa kuro nile pẹlu aburo ẹ to jẹ ọmọ oṣu mẹrin nitori mo mọ iru eeyan ti ọkọ mi jẹ, o fẹran owo ju ta-ń-dá-a-á-lẹ̀ lọ.

 

“Lati igba to ti mọ ibi ti mo wa ni ko ti jẹ ki n sinmi mọ, a a loun fẹẹ ko awọn ọmọ sọdọ, paapaa eyi to jẹ akọbi. Emi o si le yọnda ọmọ fun un nitori mi o le gba ko fi ọmọ temi ṣoogun owo, ko ma jẹ pe nṣe loluwa ẹ fi idi ṣofo lasan lori ọmọ bibi.”

 

Olujẹjọ, iyẹn Ọpẹyẹmi ti i ṣe ọkọ Ṣalewa sọ pe oun naa fara mọ ki ipinya de ba oun ati iyawo oun. Ṣugbọn o rọ ile ẹjọ lati gba awọn ọmọ to da igbeyawo ọhun pọ ki wọn si yọnda wọn foun nitori aajo pataki kan wa ti oun fẹẹ ṣe fun wọn lati ro wọn lagbara.

 

“Mo ni lati ro awọn ọmọ mi lagbara, paapaa eyi akọbi yẹn nitori àràgbé nile aye ta a wa yii, ko si si ẹni to le yi mi lọkan pada lori ẹ nitori emi ni mo lọmọ mi, ohun to ba si wu mi ni mo le ṣe fun un.”, bẹẹ lọkunrin naa sọ niwaju awọn adajọ

 

 

 

Igbimọ awọn adajọ kootu ọhun, eyi ti Oloye Ọdunade Ademọla n dari ti wa tu igbeyawo ọhun ka. Wọn paṣẹ pe ki awọn ọmọ mejeeji ṣi wa pelu iya wọn, ki baba wọn si maa fi owo ounjẹ atowo ileewe awon mejeeji ranse si iya wọn loṣooṣu lati ipase ile ẹjọ.

(11)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.