Rotimi ti wọn ka ibọn mọ lọwọ n’Igbara-Oke ti ha sọwọ ọlọpaa

Spread the love

Ọmọtogun Rotimi, ẹni aadọta ọdun, to n gbe lojule kẹwaa, laduugbo Eromi, niluu Igbara-Oke, ti ha sọwọ awọn ọlọpaa lori ẹsun pe wọn ka ibọn ati ọta mọ ọn lọwọ.

 

Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Fẹmi Joseph, ṣalaye fun wa pe ni nnkan bii aago mẹjọ alẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ to kọja lọhun-un lọwọ tẹ afurasi ọhun laduugbo Ero-Ekiti, Igbara-Oke, nijọba ibilẹ Ifẹdọrẹ. Alex Anifowoṣe lo lọọ ka mọ ṣọọbu iyawo rẹ lalẹ ọjọ yii, lo ba ni ti ọkunrin naa ko ba fẹ ki Ogun fi ẹjẹ oun wẹ, afi ko fun oun ni igo bia kan.

 

Baale ile yii pada fun un ni ọti oun, to si ni ko jokoo lori aga gbọọrọ kan to wa niwaju ṣọọbu naa, nibi to ti ni ko farabalẹ mu ọti toun ra fun un.

 

Ọti yii lo n mu lọwọ to fi bẹrẹ si i ka boroboro pe ẹnikan lo ran oun si i lati waa gbemi rẹ, loju ẹsẹ ni wọn lo kọwọ bọ apo rẹ, to si ko ọta ibọn meji jade.

 

Lẹyin eyi lo tun tu apo to gbe dani, nibi to ti fa ibọn agbelẹrọ kan yọ lati fi da Alex loju pe oun ko waa ba a ṣere rara.

 

Nibi ti wọn sọrọ de ree ti ẹni to lọọ ba naa fi n pariwo ki awọn eeyan le waa gba a silẹ lọwọ iku ojiji.

 

Awọn to wa nitosi ni wọn pa ọwọ pọ mu afurasi naa, ti wọn si fa a le ọlọpaa teṣan Igbara-Oke lọwọ.

 

Fẹmi Joseph sọ pe iwadii ṣi n tẹsiwaju lori ẹsun ti wọn fi kan ọkunrin yii, ni kete ti awọn ba pari ni yoo foju ba ile-ẹjọ.

 

 

(4)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.