Rogbodiyan l’Ekiti: Awọn ọmọ ẹgbẹ APC fi ẹbọ le awọn adari, lawọn ọlọpaa ba ya bo igboro *Bẹẹ lawọn oludije yari patapata

Spread the love

Nnkan aramanda lo ṣẹlẹ laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, ana nigba tawọn ọmọ ẹgbẹ All Progressives Congress kan ya bo sẹkiteriati ẹgbẹ naa to wa ni Ajilosun, l’Ado-Ekiti, nibi ti wọn ti gbe ẹbọ sẹnu ọna, ti wọn si n pariwo pe awọn ko fẹ awọn oloye awọn mọ.

Eyi waye lẹyin awuyewuye to ṣẹlẹ lẹyin idibo abẹle to waye lọjọ Abamẹta, Satide, to kọja, eyi ti wọn fi ija daru, tawọn olori ẹgbẹ naa l’Abuja gan-an ko si ti i ri ọna abayọ kan gboogi si i.

Ṣe lawọn ọmọ ẹgbẹ naa ti wọn ko oriṣiiriṣii akọle dani sọ pe awọn ko fẹ igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ ọhun l’Ekiti, eyi ti Oloye Jide Awẹ n dari. Wọn ni alaga naa lo ko awọn janduku wọ ibudo idibo lọjọ Satide, oun naa lo tun wa n pe fun fifagile ibo ọhun. Niṣe ni wọn gbe ẹbọ siwaju geeti olu-ile ẹgbẹ naa, ti wọn si ti ibẹ pa, wọn ni awọn ko fẹẹ ri ẹnikẹni.

Gẹgẹ bi Amofin Adeoye Aribasoye to gbẹnusọ fawọn eeyan naa ṣe sọ, ”Igbakeji adari ọdọ ẹgbẹ yii, Ademọla Adewusi, ti wọn n pe ni Ooṣa, lo ṣaaju awọn to da ibẹ yẹn ru, ṣugbọn awa ti le e danu bayii. Alukoro wa, Taiwo Ọlatunbọsun, ko awọn kaadi idanimọ jade ninu ibudo yẹn lati ko o fawọn kan, a si sọ fawọn ọlọpaa atawọn ọtelẹmuyẹ nipa rẹ.

‘’ Awọn kan tun waa lọọ ko ara wọn jọ, wọn ni ki wọn yan oludije kan bii ẹni ti gbogbo wa fọwọ si, eyi to tako ofin ẹgbẹ. Ni bayii, awa naa n lo abala kọkanlelogun ofin ẹgbẹ wa lati sọ pe a ko nigbagbọ ninu igbimọ Oloye Jide Awẹ mọ.

‘’A ti gbe igbimọ ma-jẹ-ko-bajẹ kalẹ bayii, eyi ti Ọgbẹni Kayọde Egunjọbi to jẹ alaga ijọba ibilẹ Isẹ yoo dari, ti alaga ijọba ibilẹ Ado, Michael Akinlẹyẹ, si ṣe akọwe fun. Awọn alaga ijọba ibilẹ mi-in bii ti Emure, Ẹfọn, Ikẹrẹ, Irẹpọdun/ Ifẹlodun, Mọba, ilejemeje, Ọyẹ, Ikọlẹ ati Ijero lo fọwọ si eto yii. Lọrọ kan, gbogbo wa la fọwọ si i.”

Ṣugbọn Oloye Jide Awẹ sọ pe oriṣiiriṣii eeyan ti wọnu ẹgbẹ awọn latari rogodiyan to wa nilẹ yii, awọn lo si n da wahala silẹ. O ni oun ko mọ ibi ti wọn ti ri ofin ẹgbẹ ti wọn fi da igbimọ tiwọn silẹ nitori igbimọ awọn fẹsẹ mulẹ daadaa.

Bakan naa ni Taiwo Ọlatunbọsun sọ pe oun ko mọ nipa kaadi ti wọn ni oun ko fun awọn tọọgi nitori aarin awọn oniroyin loun duro si ni gbogbo asiko naa, aworan gbogbo ileeṣẹ tẹlifiṣan ati iroyin si fidi eleyii mulẹ.

Lọsan-an ana kan naa lawọn oludije kan tun pade latari iroyin kan to n ja nilẹ pe Bọlaji Abdullahi ti i ṣe alukoro ẹgbẹ naa lapapọ sọ pe idibo ti wọn daru naa yoo tẹsiwaju lati ibi ti wọn di i de.

Dokita Mojisọla Yaya-Kọlade to gbẹnusọ fawọn eeyan naa sọ pe ẹni kan lo lọọ sọ fawọn olori ẹgbẹ l’Abuja pe awọn gba lati tẹsiwaju ninu ibo ọhun.

‘’ Ko si nnkan to jọ pe a gba lati tẹsiwaju pẹlu ibo ti wọn ti di, ko si igba ta a fẹnuko lori nnkan to jọ bẹẹ. Gbogbo awa oludije la wa nibi lọna kan tabi omiiran, nitori awọn to ti rin irin-ajo ninu wa gan-an fi ọrọ ranṣẹ. Ko si ẹnikẹni ninu wa to tako nnkan ti a kede rẹ pe ibo tuntun la maa di nitori gbogbo eeyan lo mọ pe wọn ko ka eyi ti wọn daru rara, awọn to n gbe iroyin kiri lo n ba nnkan jẹ.’’

Awọn to tun wa nibi ipade yii ni: Oloye Ṣẹgun Oni, Ọnarebu Bimbọ Daramọla, Ọnarebu Ọpẹyẹmi Bamidele, Dokita Bayọ Orire, Ọnarebu Bamidele Faparusi, Ọgbẹni Debọ Ajayi, Ọgbẹni Kọla Alabi, Ọgbẹni Diran Adeṣua, Ọgbẹni Adekunle Ẹsan, Ọgbẹni Muyiwa Olumilua, Sẹnetọ Ayọ Ariṣe, Ọmọwe Makanjuọla Owolabi ati Ọgbẹni Victor Kọlade.

Ni bayii ti wọn ti ti olu-ile ẹgbẹ naa pa, tawọn oludije si n ke tantan pe awọn ko ni i gba igbakugba kankan mọ, ibi tọrọ naa yoo ja si lawọn eeyan n reti, wọn si fẹẹ mọ bi APC yoo ṣe yan oludije rẹ ko too di ọjọ Aje, Mọnde, to n bọ.

(27)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.