Rogbodiyan da ipade INEC ru l’Ekiti

Spread the love

Niṣe lọrọ di wahala nibi ipade gbogbo awọn tọrọ kan lori eto idibo gomina ipinlẹ Ekiti lọjọ Aje, Mọnde, ana nigba tawọn kan fi ariwo da ibẹ ru. Awọn eeyan ọhun ti wọn pe ara wọn lọmọ ẹgbẹ People’s Democratic Party (PDP) ni ko jẹ ki eto ọhun pari rara ti onikaluku fi gba ile rẹ lọ.

Eto naa to waye ni Gbọngan Great Eagle Hall, to wa lọna Ikẹrẹ, l’Ado-Ekiti, ni ajọ eleto idibo (INEC) pe lati ṣalaye bi gbogbo nnkan yoo ṣe waye nibi idibo opin ọsẹ yii, bẹẹ lawọn olori agbofinro, awọn ọba, awọn oludije atawọn ololufẹ wọn wa nibẹ.

Lẹyin ti awọn ọlọpaa sọrọ ti wọn si fọkan awọn oludibo balẹ ni Ọjọgbọn Mahmood Yakubu to jẹ alaga INEC nilẹ yii naa sọrọ, bẹẹ ni wọn ṣe ere itage kekere kan lati sọ bi ibo alaafia ṣe le waye. Afi bi wọn ṣe pe Ọnarebu Samuel Ọmọtọsọ to jẹ alaga igbimọ iroyin ile igbimọ aṣofin Ekiti lati sọrọ tawọn kan bẹrẹ ariwo nigba to n darukọ Ọmọwe Kayode Fayẹmi to jẹ oludije All Progressives Congress (APC) leralera pe o n leri pe oun yoo wọle dandan.

Awọn ololufẹ ẹgbẹ APC pariwo mọ ọkunrin ọhun pe ko yee darukọ oludije awọn, ṣugbọn ariwo awọn ti PDP bo tiwọn mọlẹ, ọrọ naa si di wahala nla. Ṣe ni wọn n pariwo ‘Ẹlẹka…dibo!’, nigba to ya ni ko tiẹ sẹni to gbọ nnkan ti Ọnarebu Ọmọtọṣọ n sọ mọ. Asiko yii ni Ọlọyẹ tilu Ọyẹ, Ọba Oluwọle Ademọlaju, bẹrẹ si i parọwa si wọn, ṣugbọn wọn ko dahun.

Bi ariwo yii ṣe tẹsiwaju titi tawọn eeyan fi jade nikọọkan niyẹn, koda awọn eeyan ọhun lọ n pariwo orukọ ẹgbẹ wọn niwaju mọto Ọmọwe Kayọde Fayẹmi lasiko to fẹẹ maa lọ, wọn ko si jẹ ko tete jade.

Lasiko ti ALAROYE kuro nibẹ ni nnkan bii aago meji ọsan, gbogbo awọn to ṣagbatẹru eto naa ti fẹẹ lọ tan, o si daju pe eto naa ko tẹsiwaju.

(33)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.