Ramọn atawọn ọrẹ to ji ọkada gbe ti ha l’Owode-Yewa

Spread the love

Laipẹ yii ni ọwọ ọlọpaa tẹ awọn afurasi ọdaran kan, Ramọn Azeez, ẹni ti wọn n pe ni Iku Raymon, Adeyẹmi Usman, ati Balogun Lekan. Ẹsun ti wọn mu wọn fun ni ṣiṣe ẹgbẹ to lodi si ofin ijọba, iyẹn ẹgbe okunkun Eye. Nigba ti Ramon n ba akọroyin wa sọrọ, o ni, “ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn ni mi, ẹran ni mo n ta. Mo wa lọdọ wa lọhun-un (Owode-Yewa) ni Usman ati Lekan waa pe mi pe wọn n ja lọdọ awọn l’Owode-Idi-Iroko, ki n waa ba awọn da si i. Nigba ti a debẹ, a ko ba awọn ti wọn n ja mọ, ẹnikan ti wọn n pe ni Ẹgusi la ba. Ọrẹ mi ni ẹni ti wọn n ba ja, idi niyẹn ti mo ṣe lọ lati lọọ gbeja rẹ. Ṣugbọn nitori pe a ko ri eeyan ba ja ni Usman fi ni ki a ji ọkada ti a ba ti wọn gbe silẹ. Lẹyin ti a gbe e, ilẹ Faranse la ta a si. Loootọ, a ko mọ ẹni to ni ọkada naa. Ohun to dun mi ju ni pe ẹni kẹta wa, iyẹn Ẹgusi, ti sa lọ bayii.”

Nigba to n dahun si ibeere akọroyin wa lori bi wọn ṣe ri kọkọrọ ṣi ọkada naa, o ni: “ko si kọkọrọ nibi ọkada yii, ṣugbọn mi o mọ bi Usman ṣe ṣi i to fi ri i gbe, nitori oun lo wa a. Oun naa lo lọọ ta a, ẹgbẹrun kan Naira ni wọn si fun mi ninu owo naa. Nigba ti mo gba a, mo ri i pe owo kekere ni, niṣe ni mo fi jẹun lọjọ yii. Mo kabaamọ ohun ti mo ṣe yii. Mi o ni iya mọ, baba mi si ti di arugbo. Mo ti pe baba, ṣugbọn wọn ko mọ ohun ti wọn fẹẹ ṣe.”

Lekan sọ ni tiẹ bayii pe “ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn ni mi. Emi ni ọlọkada to gbe wọn de ibẹ lọjọ ti wọn lọọ ji ọkada yii. Mi o mọ nnkan kan nipa rẹ, iṣẹ aje lemi ṣe lọjọ naa.

“Loootọ, ọrẹ mi lawọn mejeeji laduugbo wa l’Owode, ṣugbọn ọkada ti mo fi gbe wọn debẹ lawọn eeyan ri, idi niyẹn ti wọn si ṣe waa mu mi. Nigba ti wọn mu mi, awọn ọlọpaa fiya jẹ mi, ṣugbọn mo tẹnumọ ọn fun wọn pe mi o mọ nnkan kan nipa rẹ.

“Iṣẹ ọkada ni mo n ṣe. Ọjọ buruku lọjọ ti mo gbe wọn naa, iyẹn ọjọ kọkandinlogun, oṣu to kọja. Idi ni pe niṣe ni mo kabaamọ pe mo jade nile lọjọ naa. Iwadii ti mo ṣe lọdọ awọn ti wọn jọ mu wa pọ nigba ti wọn mu wa yii ni wọn fi jẹwọ fun mi pe awọn ti lọọ ta ọkada ti awọn ji gbe naa silẹ Faranse. Ẹgbẹrun lọna igba o din diẹ (180, 000.00), ni awọn si ta a. Mi o gba kọbọ lọwọ wọn.”

Ṣugbọn nigba ti Usman n sọrọ , o ni irọ loun n pa fun wọn, oun ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ OPC. Ọmọkunrin naa ni loootọ, oun ji ọkada gbe, ṣugbọn Lekan lo waa pe oun pe awọn kan n ba oun ja, koun waa gbeja oun nibẹ. “Igba ti a maa debẹ, a ti ba Ẹgusi to ti ṣaaju wa debẹ, o si ti gba maṣinni silẹ. Emi ati Ramọni la jọọ gbe e lọ si ilẹ Faranse, ibẹ la ti fẹẹ lọọ ta a. Owo yẹn la ko fun Kẹhinde Ẹlegusi, ẹgbẹrun mẹrin Naira lo si fun mi, ko fun Ramọni ni nnkan kan rara. Mo fi owo naa jẹun ni.

‘‘Loootọ, ọmọ ẹgbẹ okunkun ni mi, ṣugbọn mo kan maa n ja ni, mi o ki i pa eeyan. Ti ọmọ ẹgbẹ Aiye ba ba mi ja, ma a pe awọn Ẹiye lati gbe mi nija. O ti to ọkada mẹfa ti mo ti ji. Ki i ṣe pe baba mi ko tọju mi o, wọn gbiyanju, ṣugbọn iya mi to ti sa lọ lati kekere lo fa a, oun lo da wa silẹ fun baba mi. Ọkunrin nikan ko le da tọju ọmọ laelae.”

Ni idahun si ibeere akọroyin wa nipa ọna ti tatuu OPC gba de ara rẹ, o ni oun ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ OPC. O ni lọjọ ti oun kọ tatuu naa, oun ko wọ aṣọ kankan sara, oun si lọọ ja. Nibẹ ni ẹnikan ti n pe oun ni OPC, idi niyẹn ti oun ṣe kuku lọọ kọ ọ sara, toun si fi maa dẹru ba ọpọlọpọ eeyan.”

Kọmisanna ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Bashir Makama, ti ni gbogbo alaye awọn afurasi naa ki i ṣe eyi ti oun nikan le gbọ. O ni dandan ni ki wọn de kootu, ki wọn si ṣalaye tẹnu wọn fun adajọ.

(1)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.