Ramatu fọbẹ ge ‘kinni’ ọkọ rẹ, o lo n ṣagbere

Spread the love

Ko sẹni to gbọ ọrọ obinrin ẹni ọdun mẹtadinlogun yii, Ramatu Tafida, ti ko kọ “haa” si iwa ọdaju to hu pẹlu bo ṣe fi ọbẹ ge ‘kinni’ ọkọ afẹsọna rẹ, Ọgbẹni Abdullahi Sabo, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn, nitori ẹsun agbere. L’Ọjọbọ Tọsidee, ọsẹ to kọja lo huwa laabi naa laduugbo Babura, nipinlẹ Jigawa.

Alukoro ajọ Nigeria Security and Civil Defence (NSCD) Jigawa to fidi ọrọ yii mulẹ fun ajọ News Agency of Nigeria (NAN), Ọgbẹni Adamu Sheu, lo ṣalaye bi iṣẹlẹ naa ṣe lọ fun wọn lẹkun-un-rẹrẹ.

Sheu ṣalaye pe loootọ ni Ramatu ati Abdullahi ti n fẹra wọn ti ṣe diẹ, koda, Abdullahi ti lọọ san ẹgbẹrun lọna ọgbọn Naira gẹgẹ bii owo-ori ọmọbinrin naa. Iṣẹ olukọ ni Abdullahi n ṣe nileewe girama ‘Government Girls Secondary School’, to wa laduugbo Babura, nipinlẹ naa.

Alukoro ajọ NSCD ni awọn ko ba ti mọ nnkan kan nipa ọrọ naa bi ko ṣe ẹnikan to sọ fawọn pe awọn ọdọ kan tinu n bi fẹẹ gbẹmi Ramatu laduugbo rẹ, iyẹn Kofar Arewa, lati fi gbẹsan iku ọrẹ wọn.

Adamu ni, “Lẹsẹkẹsẹ ta a gbọ ọrọ naa lawọn ọfisa wa gba adugbo yii lọ lati gba Ramatu silẹ lọwọ awọn ọdọ tinu n bi yii. Loootọ lawọn oṣiṣẹ wa ri ọmọbinrin yii gba, ṣugbọn sibẹ, awọn ọdọ wọnyi ko dẹyin lẹyin wọn, wọn tẹle wọn titi ti wọn fi mu Ramatu pada de ọfiisi wọn ni.

“Nigba ti awọn ọfisa wa de ọfiisi ni wọn ṣẹṣẹ too mọ nnkan to ṣẹlẹ gan-an. Ramatu funra rẹ jẹwọ pe oun loun ge nnkan ọmọkunrin afẹsọna oun nitori to fẹẹ kọ oun silẹ ba obinrin mi-in lọ.’’

Ramatu ṣalaye pe oun fẹran ọkọ afẹsọna oun yii gan-an, oun ko le fi i ṣere. O sọ pe o ti waa sanwo ori oun lọdọ awọn mọlẹbi oun. O lohun to fa a ti oun fi ge nnkan ọmọkunrin rẹ ni pe oun gbọ pe Abdullahi kan n tan oun lasan ni, o fẹẹ kọ oun silẹ lati ba obinrin mi-in lọ lẹyin to ti ba oun sun tan.

O ni nigba ti awọn jọ wa ninu ile ti awọn tun fẹẹ ṣe lọkọ-laya bi awọn ti i maa ṣe e loun beere ọrọ naa lọwọ rẹ, Abdulahi si sọ foun pe loootọ ni, bẹẹ gan-an lọrọ ri. Laimọ pe gbogbo bi oun ṣe n ba a sọrọ yii, ọbẹ ti wa lọwọ oun, ọbẹ yii loun si fi ge nnkan ọmọkunrin rẹ.

Lẹyin to huwa naa tan lo sa lọ sile awọn obi rẹ lati lọọ ṣalaye ohun to ṣẹlẹ fun wọn, ṣugbọn nibi to ti n ṣalaye fun iya rẹ lawọn ọdọ adugbo ọkọ afẹsọna rẹ ti de pẹlu ibinu, ti wọn wọ ọ jade lakata iya rẹ, ti wọn si fẹẹ lu u pa ko too di pe awọn ẹṣọ alaabo awọn ri i.

Adamu ni lẹsẹkẹsẹ tawọn gbọ nnkan to ṣẹlẹ lawọn sare pada lọ si adugbo Abdullahi, ti awọn si gbe e lọ sileewosan, ṣugbọn o ṣe ni laaanu pe ẹpa ko boro mọ, arakunrin naa ti gbẹmi-in mi ki wọn too gbe e de ileewosan.

Alukoro ajọ NSCD waa ni awọn ti gbe ẹjọ Ramatu lọ sile-ẹjọ, yoo si wa lẹwọn titi di ọjọ kẹfa, oṣu kẹsan-an, ti igbẹjọ rẹ yoo bẹrẹ ni.

(32)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.