Prince ree, awọn ọmọkunrin keekeeke lo maa n ba lo pọ l’Ekoo *O tun ko aarun eedi ran wọn

Spread the love

Awọn ọlọpaa ti ni dandan ni ki Prince Chincherem, ẹni ọdun mejilelọgbọn,  foju ba kootu nitori bo ṣe ba aye awọn ọmọdekunrin kan jẹ nipa kiko arun eedi ran wọn. Ibalopọ akọ si akọ ni Prince maa n ba awọn ọmọ naa ṣe, eyi to si ti di baraku fun un, bẹẹ lọkunrin naa funra rẹ ko mọ pe oun laisan kogboogun ti wọn tun n pe ni eedi lara. Iwadii awọn ọlọpaa fihan pe Prince ni aṣaaju ikọ awọn gee, iyẹn awọn ọkunrin to fẹran ibasun akọ si akọ lagbegbe Lẹkki.

Imohimi Edgal ti i ṣe kọmisanna ọlọpaa Eko ṣalaye pe ṣe ni ọkunrin naa maa n lo awọn ọmọdekunrin yii fun iṣẹ aṣẹwo, o maa n ba wọn sun, o si tun maa n gbe wọn fun awọn ọkunrin mi-in ti wọn fẹran iwa ko tọ naa.

Edgal ni ọrọ ti Prince tilẹ tun waa buru jai, nitori ṣe ni ayẹwo ti wọn ṣe fun un fi han pe o larun eedi lara, bẹẹ o ṣee ṣe ki ọpọlọpọ awọn ọmọ naa ti ko o lati ara rẹ.

Iwadii awọn agbofinro fi han pe awọn pasitọ meji kan pẹlu awọn oniṣowo to nifọn leeekanna ti wọn ṣi n wa, wa lara awọn to maa n ba ọkunrin afurasi yii dowo pọ.

Ọga ọlọpaa ni lọjọ kejilelogun, oṣu to kọja, ni awọn kan ri ọmọdekunrin kan to yọ jade kuro nile Prince l’Ejigbo. Nigba ti awọn araadugbo mu un ni wọn bẹrẹ si i fi ọrọ po o nifun pọ pe ki lo ṣẹlẹ to fi n yọ rin, ṣugbọn esi to fun wọn ko tẹ wọn lọrun. Lasiko naa ni wọn ri baagi kan ti ọmọdekunrin yii gbe lọwọ, ẹsẹkẹsẹ si ni wọn ni ko ṣi i, awọn fẹẹ yẹ ẹru to wa ninu rẹ wo.

Iyalẹnu nla lo jẹ nigba ti wọn ri kọndọọmu ti atọ idi ọkunrin kun inu rẹ to pọ ninu baagi naa, nigba ti wọn si dẹruba a lo jẹwọ pe Prince Chincherem ni ololufẹ oun.

Kiakia ni wọn gbe ọrọ naa lọ si teṣan ọlọpaa to wa l’Ejigbo, awọn ọlọpaa ko si fi falẹ rara ti wọn fi mu Prince ti obinrin ki i wu, ayafi ọkunrin nikan.

Ayẹwo ti wọn ṣe fun awọn mejeeji lọsibitu lo fi han pe wọn ti ko arun eedi. Ṣa, kọmisanna ọlọpaa ti ni awọn ko ni i pẹẹ gbe afurasi naa lọ si kootu, pẹlu alaye pe awọn ti gbe ọmọ naa lọ si ọdọ awọn to maa n gba awọn eeyan nimọran, ki wọn baa le tun aye rẹ ṣe.

 

(19)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.