Peli irọrun la maa fẹyin Buhari ati ẹgbẹ APC janlẹ ni Kwara -PDP

Spread the love

Ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Kwara ti ni aṣẹ ti Aarẹ Mohammadu Buhari pa fawọn adari APC nipinlẹ naa lati gba ijọba Kwara lọwọ Dokita Bukọla Saraki ninu eto idibo 2019 ko le wa si imuṣẹ.
PDP gba Aarẹ Buhari ati awọn ọmọ ẹgbẹ APC nimọran lati gbaradi fun ijakulẹ to maa ba wọn ninu eto idibo naa.
Ẹgbẹ PDP sọ pe ohun to yẹ ko jẹ Aarẹ Buhari logun, to si yẹ ko dojukọ ni gbogbo iṣẹlẹ iṣekupani to n ṣẹlẹ kaakiri orilẹ-ede Naijiria dipo bo ṣe n wa gbogbo ọna lati gbakoso ipinlẹ Kwara. Ẹgbẹ ọhun ni ki APC yee la ala ti ko le ṣẹ.
Bakan naa ni wọn fi aidunnu wọn han si awọn iṣẹlẹ iṣekupani to n ṣẹlẹ kaakiri orileede yii, wọn si fi idaniloju han pe awọn araalu yoo ṣatilẹyin fun awọn nipinlẹ Kwara, nipa bẹẹ, awọn yoo jawe olubori nibi eto idibo gomina nipinlẹ naa lọdun to n bọ.

(1)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.