PDP pariwo: Wọn tun fẹẹ we ẹsun mi-in mọ Saraki ati Ekweremadu lẹsẹ lati yọ wọn nipo*Irọ lẹ n pa mọ wa-APC

Spread the love

Ko ti i sẹni to mọ ọjọ ti wahala to n lọ laarin olori ile igbimọ aṣofin, Bukọla Saraki ati awọn aṣaaju ẹgbẹ APC yoo tan nilẹ, bi ko si jẹ pe ẹnikan rẹyin ẹni keji, ko jọ pe ọrọ naa yoo tan bọrọ. Ni Sannde ọsẹ yii ni alukoro ẹgbẹ oṣelu PDP, Ọgbẹni Kọla Ologbodiyan, sọ ninu atẹjade kan pe ẹgbẹ oṣelu APC n wọna lati tun lo ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ilẹ wa ati ajọ to n ri si ṣiṣowo ilu mọkumọku lati we awọn ẹsun awuruju kan mọ Saraki ati igbakeji rẹ nile igbimọ aṣofin agba, Ekweremadu, lẹsẹ, leyii ti yoo mu ki wọn fi panpẹ ofin gbe wọn, ti wọn yoo si ti wọn mọle, ki awọn aṣofin APC le rọna yọ wọn nipo.

Sannde, ọjọ Aiku, ọsẹ yii, lo sọrọ naa niluu Abuja. Ologbodiyan ni wọn fẹẹ gbe igbesẹ naa lati ri i pe awọn olori ile mejeeji ko si nitosi lasiko ti wọn ba fẹẹ jokoo lonii, ọjọ Iṣẹgun, fun ipade apero wọn. Eyi yoo mu ki awọn kan ti wọn jẹ sẹnetọ ninu ẹgbẹ oṣelu APC, ṣugbọn ti wọn kere niye yoo ti sọ pe awọn yọ awọn eeyan mejeeji nipo, ti wọn yoo si fi meji ninu wọn rọpo wọn. Bẹẹ lo fi kun un pe ileeṣẹ aarẹ n gbimọ-pọ pẹlu awọn EFCC yii lati mu awọn mọlẹbi awọn aṣaaju mejeeji yii, ki wọn si fi da wahala si wọn lọrun.

Ẹgbẹ PDP ni bi ijọba ṣe n fi dandan le e pe awọn aṣofin gbọdọ jokoo pajawiri lati fọwọ si awọn eto iṣuna kan ati awọn kan ti ijọba Buhari ṣẹṣẹ yan sipo jẹ ọna lati mu erongba wọn ṣẹ. O fi kun un pe ohun to ba ni lọkan jẹ ninu ọrọ naa ni pe eto iṣuna ajọ eleto idibo tijọba n pariwo pe ohun lawọn tori ẹ fẹ ki awọn aṣofin jokoo, ki wọn le fọwọ si i yii, lati inu oṣu keji, ọdun yii, ni ajọ eleto idibo ti fi ranṣẹ si ileeṣẹ Aarẹ, to si yẹ ki wọn ti fi ranṣẹ si awọn aṣofin ki wọn ti ṣiṣẹ lori rẹ. Ṣugbọn ileeṣẹ Aarẹ mọ-ọn-mọ da eto naa duro di oṣu keje, ọdun yii, to jẹ asiko ti awọn aṣofin maa n lọ fun isinmi wọn.

Bẹẹ ni wọn bu ẹnu atẹ lu Adele Aarẹ, Ọjọgbọn Yẹmi Oṣibajo, pe ko yee dibọn bii ẹni ti ko mọ nipa igbesẹ ti awọn ẹgbẹ APC fẹẹ gbe yii, wọn ni ki i ṣe pe o mọ nipa rẹ nikan kọ, wọn jọ pinnu rẹ ni.

Alukoro ẹgbẹ PDP yii waa ke si awọn ọmọ Naijiria, to fi mọ awọn olori orileede agbaye gbogbo lati da si ọrọ naa, nitori igbesẹ ti ijọba Buhari ati ẹgbẹ APC lapapọ n gbe le ṣakoba fun ijọba awa-ara wa ati iṣọkan Naijiria.

Ṣugbọn adele alukoro ẹgbẹ oṣelu APC, Ọgbẹni Yẹkini Nabena, ti ni ko soootọ kankan ninu awọn ẹsun ti ẹgbẹ PDP fi kan awọn, o ni ọrọ awọn eeyan naa da bii ẹni ti ko ṣe nnkan itufu, to wa n kiyesi ẹhinkule. O ni ti Bukọla ati igbakeji rẹ ba mọ pe awọn ko ṣe ohun ti ko dara, ko yẹ ki ẹru maa ba wọn. O ni gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ awọn, Adams Osiomhole, ṣe sọ, gbogbo ọna to tọ labẹ ofin lawọn yoo fi yọ awọn eeyan naa nipo.

Ṣugbọn awọn aṣofin to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ti sọ pe mimi kan ko le mi olori awọn aṣofin naa. Wọn ni gbagbaagba lawọn duro sẹyin rẹ, awọn si ni igbẹkẹle ninu rẹ gẹgẹ bii adari awọn, nidii eyi, gbogbo ọna lawọn yoo gba lati ri i pe erongba awọn kan lati yọ Saraki ati igbakeji rẹ nipo ko wa si imuṣẹ.

Nigba ti awọn aṣofin yii ba jokoo lola ni ohun gbogbo yoo too foju han.

(22)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.