Patrick ji aja gbe l’Ondo

Spread the love

Adugbo Ọlapẹloye ni ọwọ ti tẹ Patrick Osemujoye, to n gbe laduugbo Yaba, niluu Ondo, wọn ni ṣe lo fẹẹ ji aja gbe. Gẹgẹ bi alaye ti ẹni to ni aja naa, Esther Akinṣara, ṣe fun wa, o ni odidi ọjọ mẹta loun fi n wa aja yii. Ọjọ Ẹti, Furaidee, lo loun kọja laduugbo Yaba, lojiji loun si ri aja oun to sọnu ti ẹnikan so okun mọrun rẹ, to si fi kọ ṣia.
Nigba ti aja naa ri olowo rẹ nitosi lo bẹrẹ si i yọ mọ ọn, nigba naa loun too fidi rẹ mulẹ pe aja oun ni wọn so mọlẹ. Ọkunrin kan ti wọn n pe ni Idowu Adegoke lo ni o kọkọ da oun lohun, to si sọ pe ki i ṣe aja oun ni wọn so mọlẹ.
Awọn eeyan lo lọ si teṣan Yaba, ti wọn si fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa leti, ko si pẹ rara ti wọn fi debẹ.
Lẹsẹkẹsẹ ti Patrick ri awọn ọlọpaa lo jẹwọ pe oun ji aja naa gbe ni, ati pe Ọjọruu, Wẹsidee, to kọja ni oun ji i nigba ti oun n ti ibi-iṣẹ bọ. O ni lẹyin ti oun ji i gbe tan loun tun un ta fun ọkunrin kan ti wọn n pe ni Ẹba, to n gbe itosi ọdọ oun.
Ati ẹni to ra aja naa, ati ẹni to ta a lawọn ọlọpaa ko lọ si teṣan wọn, nibẹ ni wọn si wa ni gbogbo asiko ti a fi n ko iroyin yii jọ.
Nigba ti Patrick n ba akọroyin wa sọrọ, o ni aṣiṣe nla ni iṣẹlẹ naa jẹ foun, o ni ki awọn ọlọpaa ba oun bẹ obinrin to ni aja naa ko ma binu.

(1)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.