Pasitọ fun aburo iyawo rẹ loyun n’Ileṣa O ni Ọlọrun lo paṣẹ foun lati ṣe bẹẹ

Spread the love

Awọn agba bọ, wọn ni ko sohun tuntun labẹ ọrun mọ, ṣugbọn sibẹ naa, awọn iṣẹlẹ kọọkan maa n ṣẹlẹ, eyi to maa n fa a ti eeyan tun fi maa n wo o pe awọn ohun tuntun ṣi tun n ṣẹlẹ nile-aye. Iru iṣẹlẹ bẹe lo waye ni agbegbe Alejolowo, Ilaye, nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ileṣa, nigba ti Pasitọ Bukọla Ajenifuja ṣadeede ki aburo rẹ, Yẹmisi, mọlẹ, to si fun ọmọbinrin naa loyun, koda, iwadii wa fi han pe oyun oṣu mẹfa lo ti wa ninu rẹ bayii.

Ọkunrin kan ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ, Ọgbẹni Babalọla Ajayi, ṣalaye fun akọroyin wa pe nigba ti oyun inu Yẹmisi di oṣu meji ni pasitọ yii sọ fun iyawo rẹ, iyẹn Abilekọ Adenikẹ, pe Ọlọrun sọ fun oun pe ki oun fẹ iyawo keji, bẹẹ aburo rẹ gan-an, iyẹn Yẹmisi, ni oun ri loju iran naa. Pasitọ Ajenifuja ni ko ni i daa, ti iyawo oun ba jẹ oludena aṣẹ Ọlọrun, fun idi eyi, o mu un ni dandan fun un pe ko fọwọ si i ki oun fẹ aburo rẹ gẹgẹ bii iyawo.

Gbogbo bi iṣẹlẹ yii ṣe n ṣẹlẹ ni Adenikẹ ko jẹ ki awọn obi rẹ mọ nipa rẹ, nitori oun pẹlu aburo rẹ ko yọju sile ọdọ rẹ rara.

Lọwọlọwọ bayii, inu ile pasitọ naa ni Yẹmisi n gbe. Gbogbo akitiyan akọroyin wa lati ba Yẹmisi ati pasitọ naa sọrọ lo ja si pabo, nitori wọn ni wọn ti lo si irinajo lasiko ti akọroyin wa de ile wọn.

 

(72)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.