Oye Iyalọja di wahala n’Ibadan, eeyan mẹta lo fara pa

Spread the love

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ọlọpaa ateeyan meji mi-in lo fara gba ninu ọja Bodija, n’Ibadan, lasiko rogbodiyan to waye lori ọrọ oye Iyalọja ọja naa.

Titi di ba a ṣe n wi yii, awọn meji ni wọn n ja si ipo Iyalọja yii. Awọn ara ọja ọhun nikan lọrọ yii han si tẹlẹ, afi lỌjọruu, Wẹsidee, to kọja, nigba ti awọn ọdọ ọja ọhun kan ya bo ileẹgbẹ awọn ọlọja pẹlu ibọn atawọn nnkan mi-innibi ti wọn ti n ṣafihan Alhaja Sikirat Adebayọ (Tantọlọun) gẹgẹ bii Iyalọja wọn, ti wọn si da eto alarinrin ọhun ru.

Ọkan ninu awọn  to n ja si ipo yii, Abilekọ Victoria Onipẹde, la gbọ pe Olubadan ana, Ọba Samuel Odugade, fi jẹ Iyalọja nigba aye ẹ, ṣugbọn ti ko sẹni to mọ ọn gẹgẹ bii adari ọja ninu awọn ontaja ninu ọja nla naa.

Iwadii ALAROYE fidi ẹ mulẹ pe laipẹ yii ni iya naa lọọ ṣalaye fun Olubadan to wa lori itẹ bayii, Ọba Saliu Adetunji, laafin pe Olubadan ana ti fi oun jẹ Iyalọja, ṣugbọn awọn ara ọja ko fun oun lanfaani lati ṣe ojuṣe oun gẹgẹ bii olori wọn.

Lẹyin to ti gba atilẹyin Ọba Adetunji, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, to kọja, lo ko awọn ọlọpaa lẹyin pẹlu ọpa aṣẹ Olubadan lọwọ, wọn si yipo inu ọja naa kaakiri lati fi han awọn ara ọja pe oun ni Iyalọja wọn tuntun.

Ṣugbọn lati ọdun mẹrin sẹyin lawọn igbimọ eleto ọja Bodija ti dibo yan Alhaja Adebayọ, ẹni tawọn eeyan tun mọ si Tantọlọhun sipo Iyalọja. Ijo ti Abilekọ Onipẹde atawọn eeyan ẹ jo kiri ọja yii lo jẹ ki awọn ijoye ọja yooku naa taari Alhaja Tantọlọhun siwaju, ti awọn naa si tẹle e yipo ọja kiri lati sọ fun awọn ontaja gbogbo pe Iyalọja ko pe meji, oun kan ṣoṣo ti wọn dibo yan lọjọ wo nihin-in naa ṣi lolori wọn.

Ni kete ti wọn pari eyi ni wọn ṣeto ipade oniroyin ninu gbọngan ile ẹgbẹ ọja naa lati ṣalaye ohun to n ṣẹlẹ fun gbogbo aye. Ṣugbọn ere lawọn kan sa kuro nibẹ pẹlu bi idarudapọ ṣe ṣẹlẹ lojiji. Awọn alatilẹyin Abilekọ Onipẹde lo deede ja waya ti wọn fi fa ina wọle lati ara ẹrọ amunawa danu, ti gbogbo ibẹ si ṣokunkun rabidun lẹẹkan naa.

Oṣiṣẹ to n mojuto ile-ẹgbẹ ọhun lawọn onijagbọn to dihamọra pẹlu ibọn, ada ati akufọ igo yii ti kọkọ digbo lu, ti ọkunrin naa si sa asala fun ẹmi ara ẹ. Bi awọn ẹruuku si ṣe wọle ni wọn bẹrẹ si i lu awọn eeyan nilukulu ti eeyan meji si tibẹ fara pa.

Ọkan ninu awọn ọlọpaa to n gbiyanju lati pana ija ọhun lẹnikẹta tọwọ iya awọn ipata ba. Bo ṣe n lu awọn janduku naa lawọn paapaa n ba a wọya ija lai bẹru ibọn to gbe lọwọ. Ọna ti wọn yoo gba lu ọkunrin agbofinro naa ṣe leṣe ni wọn si n wa ki wọn too pada sa lọ nigba ti agbofinro naa mura lati fi ibọn awọn ẹ da wọn lẹ́kun arifin.

Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ lori iṣẹlẹ yii, Babalọja ọja Bodija, Alhaji Sumaila Jimọh,  ṣalaye pe, “Alhaja Sikirat nikan loun atawọn ara ọja mọ si Iyalọja Bodija nitori oun ni gbogbo ara ọja dibo yan pẹlu atilẹyin ijọba.

“Ẹgbẹ mọkanlelogun (21) lo wa ninu ọja yii. Gbogbo ẹgbẹ yii lo yan aṣoju ti wọn fi dibo yan Iyalọja. Awọn ta a jọ dibo nigba naa ti wọn ko wọle ni wọn lọọ gbe ẹni ti wọn fẹẹ fi jẹ Iyalọja lọna ti ko bofin mu yii wa. obinrin yẹn ko si si ninu eyikeyii ninu ẹgbẹ mọkọọkanlelogun to wa ninu ọja yii.”

Gẹgẹ bo ṣe sọ siwaju, “ni ọgbọnjọ (30), oṣu kin-in-ni, ọdun 2015, ni ijọba fun emi Alhaja Sikirat ni iwe eri gẹgẹ bii Babalọja ati Iyalọja ọja Bodija. Awa pẹlu olori ẹgbẹ ọlọja nijọba ibilẹ Ariwa Ibadan ni wọn jọ fun ni iwe naa. Gomina ipinlẹ Ọyọ nigba yẹn, Sẹnetọ Abiọla Ajimọbi ati Ọnarebu Idris Lapade to jẹ alaga ijọba ibilẹ Ariwa Ibadan nigba yẹn pẹlu Alhaji Dauda Ọladapọ ti i ṣe Babalọja ipinlẹ Ọyọ wa nikalẹ lọjọ naa lati ṣatilẹyin ijọba fun wa.”

O waa rawọ ẹbẹ si Ọba Adetunji lati ma ṣe lọwọ si ọrọ iyansipo Iyalọja mi-in,nitori awọn ara ọja naa ti ni Iyalọja wọn ti wọn yan sipo ọhun pẹlu idibo.

Ọkan ninu awọn ontaja Bodija  ṣalaye fakọroyin wa pe  “awọn to n ṣe owo ọja baṣubaṣu ko too di pe a dibo yan awọn Iyalọja ati Babalọja fun igba akọkọ ninu itan ọja yii ni wọn lọọ gbe Abilekọ Onipẹde wa lati tako Iyalọja, awọn eeyan yii ko si to nnkan, diẹ ninu awọn ọdọ ọja ti wọn fẹẹ gbọna aitọ de ipo aṣẹ lo n tẹle e kiri lati ditẹ gbajọba.”

Nigba to n ba akọroyin wa sọrọ, Alhaja Tantọlọhun sọ pe, “nigba ti Onipẹde atawọn  ẹmẹwa ẹ ṣe iwọde tiwọn, wọn gba iwaju ṣọọbu mi nibi kọja, mi o ba wọn ja, awọn ọlọpaa to tẹle wọn ki mi, emi naa si ki wọn. Ṣugbọn lọjọ tawọn ara ọja atawọn agbaagba ọja ṣe atilẹyin wọn fun emi lo di pe wọn waa da eto wa ru.

“A ko mọ obinrin yẹn tẹlẹ, ko si ninu ẹgbẹ ọja yii. Awọn ọmọ kan ni wọn kan gbe e wa lati fi tako mi. Bẹẹ, emi ni gbogbo ọja dibo yan, ọjọ kan naa ni wọn dibo yan emi ati babalọja. Awa si lẹni akọkọ to maa joye yẹn nitori oye alaga ọja la n jẹ tẹlẹ.”

Akitiyan akọroyin wa lati gbọ tẹnu Olubadan lori ọrọ yii ko seso rere pẹlu bi Ọgbẹni Adeọla Ọlọkọ ti i ṣe akọwe Ọba Adetunji ko ṣe gbe ipe, ti ko si tun fesi si atẹreanṣẹ ti oniroyin yii fi ṣọwọ sori ẹrọ ibanisọrọ rẹ.

Iyalọja ti ijọba ipinlẹ Ọyọ yan, Alhaja Tantọlọhun atawọn oloye ọja yooku ti wọ eyi ti Olubadan yan (Onipẹde), lọ si kootu bayii, wọn fẹ ki ile-ẹjọ fofin de obinrin naa lati yee maa ri ara ẹ gẹgẹ bii Iyalọja ọja Bodija. Alhaji Jimọh ti i ṣe Babalọja ọja naa lo fidi eyi mulẹ f’ALAROYE.

(12)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.