Ọwọ ti tẹ Victoria to ja mọto gba lọwọọ Dokita

Spread the love

Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti tẹ Victoria Odion ti wọn fẹsun kan pe oun atawọn kan ti wọn ti sa lọ bayii gba mọto Toyota Camry lọwọ dokita kan niluu Ileefẹ, bẹẹ lo si ti foju bale-ẹjọ.

Victoria ọmọ ọdun mejilelogun lawọn ọlọpaa fẹsun kan pe o huwa naa ni nnkan bii aago mọkanla aabọ aarọ ọjọ kẹrin, oṣu kẹta, ọdun yii lagbegbe All Souls Chapel, ninu ọgba Ọbafẹmi Awolọwọ Yunifasiti, niluu Ileefẹ.

Inspẹkitọ Sunday Ọsanyintuyi to n ṣoju ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe ṣe ni Victoria atawọn ẹgbẹ rẹ gbimọ pọ, ti wọn si ja Dokita Fagbohun Babatọpẹ lole lọjọ naa.

Ọsanyintuyi ni wọn gba mọto Toyota Muzzle Camry alawọ ewe to ni nọmba EQ 299 ABJ, eleyii ti owo rẹ to miliọọnu mẹrin o din ẹgbẹrun lọna igba naira lọwọ ọkunrin naa. Bakan naa ni wọn tun gba foonu Samsung ti owo rẹ jẹ ẹgbẹrun lọna mẹrindinlọgbọn naira.

O ni abala irinwo-o-din-mẹwa ati okoolelẹẹdẹgbẹta-o-din-marun-un iwe ofin iwa ọdaran ti ọdun 2002 tipinlẹ Ọṣun n lo koro oju si iwa olujẹjọ, bẹẹ ni ijiya si wa nibẹ pẹlu.

Nigba ti wọn ka awon ẹsun mejeeji si olujẹjọ leti, o ni oun ko jẹbi wọn, bẹẹ naa ni agbẹjọro rẹ, Ben Adirieje, bẹbẹ fun beeli olujẹjọ pẹlu irọrun. O ni ko ni i sa lọ fun igbẹjọ, o si ti ṣetan lati fi oniduuro to lorukọ silẹ.

Ṣugbọn Adajọ Ọlalekan Ijiyọde sọ pe oun ko le faaye beeli silẹ fun olujẹjọ lai jẹ pe agbẹjọro rẹ mu iwe wa nilana ofin.

Ijiyọde waa paṣẹ pe ki awọn agbofinro lọọ fi olujẹjọ pamọ sọgba ẹwọn titi ti ile-ẹjọ yoo fi sọrọ lori lẹta beeli ti agbẹjọro rẹ ba mu wa sile-ẹjọ.

O waa sun igbẹjọ siwaju si ogunjọ, oṣu kẹfa, ọdun yii.

(38)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.