Ọwọ tẹ Yọmi ati ọrẹ ẹ ti wọn fẹẹ ji igbakeji ọga kọsitọọmu gbe

Spread the love

Ọwọ ileeṣẹ awọn ọlọpaa ipinlẹ Eko ti tẹ awọn ọkunrin meji kan, Yọmi Odudare ati Olugbenga Ojo, lori ẹsun pe wọn pinnu lati ji igbakeji ọga kọsitọọmu gbe, ṣugbọn aṣiri wọn pada tu.

Gẹgẹ bi Agbẹnusọ ọlọpaa nipinlẹ naa, Chike Oti, ṣe wi ninu atẹjade to fi sita, o sọ pe awọn ọlọpaa agbegbe ‘D Division’ to wa ni Mushin, niluu Eko, lo mu awọn eeyan naa.

O ṣalaye pe kọmisanna ọlọpaa, Edigal Imohim, lo paṣẹ pe ki awọn agbofinro bẹrẹ iṣẹ lori ẹnikan ti wọn lo n pe aburo igbakeji ọga kọsitọọmu ọhun, iyẹn Yisa Theophilus, lori foonu nipa okoowo.

Ohun ti wọn ri gba mu ni pe ẹni to n pe aburo igbakeji ọga kọsitọọmu yii, iyẹn Yọmi Odudare, jẹ ogbologboo ọdaran, to si tun jẹ ọmọ onilẹ.

Ọgbọn tawọn ọlopaa naa da pe ẹnikan fẹẹ ra ilẹ ni wọn fi ri Yomi mu. Bi wọn ṣe mu un lo ti jẹwọ pe loootọ lawọn fẹẹ ji igbakeji kọsitọọmu atawọn ẹbi ẹ gbe. O ni ẹnikan to ti figba kan jẹ dẹrẹba fun ẹgbọn igbakeji ọga kọsitọọmu lo gbe iṣẹ naa fawọn.

Idi niyi ti wọn fi dọgbọn tan Olugbenga Ojo, ti wọn si mu un. Erongba awọn ajinigbe mejeeji naa ni lati kọkọ mu Theopilus, ko to di pe wọn ji ẹgbọn ẹ naa gbe.

Oti waa sọ pe iwadii awọn ṣi n tẹsiwaju lori awọn tọwọ tẹ naa, bẹẹ lo ni komiṣanna ti gba awọn araalu nimọran lati maa kiyesara lati ba eeyan dowo pọ.

Capt; Awọn ajinigbe meji tọwọ te

(63)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.