Ọwọ tẹ Sanjọ to fẹẹ fun ẹlẹwọn ni igbo ninu kootu l’Oṣogbo

Spread the love

Afi bii igba ti aye n ṣe Hammed Sanjọ, ọmọkunrin ti ko ti i le ju ọgbọn ọdun lọ, pẹlu bo ṣe rọra di igbo sinu ọra dudu kekere kan, to si fẹẹ dọgbọn fun awọn afurasi ti wọn ko wa si kootu Majisreeti kan niluu Oṣogbo lọsẹ to kọja.

Bi Sanjọ ṣe n ṣe ninu kootu lo mu ifura lọwọ, tori bo ṣe n wo hanran-hanran bii ẹni ti aja n le lọ, naa ni ara rẹ ko balẹ rara nibi to jokoo si, bẹẹ lo n sun mọ ibi ti awọn afurasi jokoo si, idi niyi ti awọn oṣiṣẹ ọgba ẹwọn ti wọn ko awọn afurasi naa wa ṣe sọ pe ko jade ninu kootu.

Ṣugbọn ori ti yoo jẹ ọbẹ to san, bi wọn ba ro ẹfọ fun un, o di dandan ko rọmi si i, ṣe ni Sanjọ di Akintọla taku, ko dahun, o jokoo sibẹ, afi igba ti wọn too fagidi le e jade kuro ninu kootu.

Bo ṣe jade lo bẹrẹ si i sa lọ, idi niyẹn tawọn oṣiṣẹ ọgba ẹwọn fi bẹrẹ si i le e lati mọ nnkan to n le e, o si to iṣẹju bii mẹrin ki wọn too ri i mu.

Nigba ti wọn mu un, wọn yẹ ara rẹ wo, ibẹ ni wọn si ti ba igbo to di sinu ọra dudu. Lẹyin ti wọn wo oju Sanjọ daadaa, wọn ni ko pẹ rara to ṣẹṣẹ kuro lọgba ẹwọn ilu Ileṣa, lori ẹsun kan ti wọn fi kan an.

Ṣe ni Sanjọ bu sẹkun gbaragada, o ni ki wọn ṣaanu oun, o ni owo loun waa fun awọn ọrẹ oun ti wọn ko wa si kootu lati ọgba ẹwọn ilu Ileṣa.

Sanjọ, ẹni to sọ pe iṣẹ telọ loun n ṣe sọ pe ṣe loun maa n lo igbo ti wọn ba lapo oun fun iṣẹ. Lẹyin naa ni wọn fa a le awọn ọlọpaa lọwọ.

(12)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.