Ọwọ tẹ Oriọla, alagbẹdẹ ti wọn lo n ko ibọn fawọn adigunjale

Spread the love

Ibi tọrọ ọkunrin ẹni ọdun marundinlaaadọta kan, Oriọla Tọba, yoo ja si ko ti i ye oun funra rẹ pẹlu ẹsun tawọn ọlọpaa fi kan an pe oun lo n ko ibọn fawọn adigunjale to n da Ado-Ekiti ati agbegbe rẹ laamu.

Alaye ti CP Amba Asuquo to jẹ kọmiṣanna ọlọpaa Ekiti ṣe ni pe ni nnkan bii aago meji aabọ oru ọjọ kẹrinla, oṣu kin-in-ni, ọdun to kọja yii, lọwọ tẹ awọn afurasi adigunjale kan lagbegbe Iropora ati Ipẹrẹ Ekiti, iyẹn Oriọla ati ọmọkunrin ẹni ọdun mejilelogun kan, Ojo Ayọdeji.

Nigba tiwadii bẹrẹ lo han pe awọn eeyan naa ni wọn ko ibọn ati ọta-ibọn fawọn afurasi adigunjale kan tọwọ tẹ ni wakati diẹ si asiko naa.

Amba ni Oriọla ati Ojo mọ pe adigunjale lawọn ti wọn n ko ibọn fun, eyi ni wọn ṣe jẹbi ẹsun igbimọ-pọ ṣiṣẹ ibi ati idigunjale.

Awọn nnkan ti Amba sọ pe awọn ọlọpaa ba lọwọ awọn afurasi yii ni ibọn oloju-meji kan, ibọn ṣakabula mẹjọ, ibọn kekere mẹta, maṣinni jorinjorin, ada meji, ọta-ibọn kan ati aake UTC kan.

Ṣugbọn Oriọla ni oun ko mọ nipa ẹsun tawọn ọlọpaa fi kan oun nitori iṣẹ alagbẹdẹ loun n ṣe, oun n fi ibọn rirọ ṣiṣẹ ṣe ni. O ni oun ko mọ nipa awọn adigunjale ti wọn loun ko ibọn fun, bẹẹ loun ko ri ọkankan ninu wọn ri.

 

(11)

1 Comment

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.