Ọwọ tẹ Ọlajide, ayederu were to n lu awọn eeyan ni jibiti

Spread the love

Awọn ọlọpaa ti fi panpẹ ọba gbe ayederu were kan ti wọn fura si pe o n lu awọn eeyan ilu Akurẹ ni jibiti, Ọlajide Ọlasanoye. Wẹsidee, ọsẹ to kọja yii, ni wọn mu un lagbegbe Gareeji Benini, loju ọna marosẹ Akurẹ si Ọwọ.

 

Gẹgẹ bi obinrin kan to n taja ninu gareeji  naa ṣe sọ fun wa, o ni o ti le lọdun mẹta sẹyin ti wọn ti mọ were ọhun lagbegbe naa, ti ko si niṣẹ meji ju ko maa tọrọ owo lọwọ awọn eeyan lọ.

 

Laipẹ yii lo ni awọn eeyan agbegbe ọhun bẹrẹ si i fura si irin ẹsẹ were ọhun, leyii to mu ki wọn lọọ fẹjọ rẹ sun lagọọ ọlọpaa.

 

A ri i gbọ pe ọpọlọpọ owo ni wọn ba ninu apo nla kan ti were ọhun maa n fa lọwọ nigba ti wọn tu u.

 

Ohun to fu awọn eeyan lara ju lori ọrọ rẹ ni ọna to gba to awọn owo ti wọn ba ninu apo ọwọ rẹ jọ, niṣe lo to wọn, to si di awọn owo naa lọtọọtọ gẹgẹ bi wọn ṣe tobi si.

 

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Fẹmi Joseph to jẹ alukoro ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, sọ fun wa pe gbogbo irisi afurasi naa lo mu ifura lọwọ, nitori pe iwadii ti wọn ṣe lori ẹsun ti wọn fi kan an fidi ẹ mulẹ pe ki i ṣe ojulowo were.

 

O ni awọn ọlọpaa ti ṣetan lati gbe furasi ọhun lọ sileewosan awọn alarun ọpọlọ, nibi ti wọn yoo ti ṣayẹwo ipo ti ọpọlọ rẹ wa.

 

(89)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.