Ọwọ tẹ obinrin to fẹẹ fi orukọ Alaafin lu Oluwo ni jibiti

Spread the love

Aṣe loootọ ni pe ọjọ gbogbo ni tole, ọjọ kan ṣoṣo bayii ni ti oni nnkan. Sinkun lọwọ tẹ ọmọbinrin kan ti ẹnikẹni ko morukọ rẹ, ẹni to ti n fi ọpọ oṣu sẹyin fi orukọ awọn eeyan nla nla lu jibiti kaakiri.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ṣe lobinrin naa, ẹni ti yoo ti to ogoji ọdun mura daadaa, to si mori le aafin Oluwoo tilu Iwo, nipinlẹ Ọṣun, Ọba Adewale Akanbi, laaarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja.
Nigba to debẹ, o sọ fun awọn to ba lagbala aafin pe Oluwoo loun fẹẹ ri, wọn beere ibi to ti wa, o si sọ fun wọn tẹrin-tẹrin pe lati ọdọ Iku baba yeye, Alaafin tilu Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyẹmi, loun ti wa.
Kia lawọn yẹn bẹrẹ si i ki i ni mẹsan-an mẹwaa, wọn ni ko jokoo kawọn lọọ fi to Kabiyesi leti pe alejo nla ba baba laafin o. Bi Oluwoo naa ṣe gbọ pe lati ọdọ Alaafin lalejo oun ti wa, o fi nnkan to n ṣe silẹ, o si yọju sibi ti alejo naa jokoo si.
Ṣugbọn iri-ni-si niṣe-ni-lọjọ, bi Oluwoo ṣe ri obinrin to ti bora tan yii, o fura pe ẹtan le wa ninu ọrọ rẹ. Lẹyin ti Kabiesi ki i daadaa, o sọ fun un pe oun n pada bọ.
Bayii ni Ọba Adewale Akanbi wọnu iyẹwu lọ, o pe foonu Alaafin Adeyẹmi lati mọ boya ootọ loniṣẹ wa lati ọdọ baba, iyalẹnu lo si jẹ fun Oluwoo nigba ti Alaafin sọ fun un pe oun ko ran ẹnikẹni niṣẹ siluu Iwo.
Oluwoo la ọrọ mọlẹ niwaju obinrin yii atawọn ijoye pẹlu awọn araalu ti wọn wa laafin lasiko iṣẹlẹ naa, bẹẹ lobinrin yii ko mọ nnkan to le sọ mọ, bo ṣe n woke lo n wolẹ.
Ṣugbọn dipo ki wọn sọ ọrọ naa di iṣu ata yan-an-yan-an fun ọmọbinrin yii, Oluwoo, gẹgẹ bii ọba to fẹran gbogbo awọn eeyan rẹ beere ohun to ri to fi hu iru iwa bẹẹ. Lasiko iwadii ni wọn fi idi rẹ mulẹ pe ọmọ bibi ilu Iwo lọmọbinrin naa, ati pe atijẹ-atimu lo sọ ọ di ẹni to n lu jibiti kaakiri ilu.
Ni bayii, ohun ti a fidi rẹ mulẹ latinu Aafin Oluwoo ni pe Kabiesi ti pinnu lati ran ọmọbinrin naa lọwọ koun naa le jeeyan laye, ko si le jawọ ninu iwa to n hu kaakiri yii.

(72)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.