Ọwọ tẹ Musa to n ba ọmọkunrin ẹgbẹ ẹ lo po l’Ekoo

Spread the love

Lọjọ Eti, Fraide, ọsẹ to kọja ni kọmiṣanna fawọn ọlọpaa nipinlẹ Eko, Imohimi Edigal ṣafihan ọmọ ogun ọdun kan, Musa Mohammed, lori ẹsun pe o n ba ọmọ ọdun mejila toun naa jẹ ọkunrin lo pọ.
Gẹgẹ bi ọga ọlọpaa naa ṣe wi, o ni lati ẹka ileeṣẹ awọn to wa ni Oke-Odo ni wọn ti fọmọ Hausa naa ranṣẹ sawọn lori ẹsun yii ati pe Abdulahi Sọdig ni wọn pe orukọ ọmọ naa.
Iwadii fi ye wa pe inu iho idi ọmọ naa ni Musa n ki kinni abẹ ẹ bọ lati ẹyin, ati pe o ti wọ ọ lara, ko si mọ igba tawọn eeyan ka oun atọmọ kekere ti wọn lo fi tipa ba ṣe kinni mọ ibi to ti n ṣe e naa.
Awọn araadugbo naa ti kọkọ fi lulu ba tiẹ jẹ ko too di pe wọn fa a le awọn ọlọpaa Oke Odo lọwọ, tawọn yẹn ko si fọrọ ẹ falẹ rara ti wọn fi fi i sọwọ si olu ileṣẹ wọn ni Ikẹja.
Nigba ti ọga ọlọpaa naa ṣafihan ẹ, o sọ pe nnkan to buru ni Musa se, ati pe o ti pẹ ti wọn ti maa n pariwo pe ko daa ki ọkunrin ati ọkunrin maa bara wọn sun, to tun waa jẹ pe ọmọ kekere lo fi tipa ba ṣe e, o lo di dandan ko foju wina ofin.
O sọ pe bii igba teeyan ba da ọran mọran loun ka nnkan ti Musa ṣe si, o lawọn ti fi i sọwọ si ẹka awọn to n ri si iwa to hu naa, ti wọn si ti bẹrẹ iwadii wọn loju ẹsẹ.

(35)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.