Owo te Khalid to ji ero itewe meji l’Osogbo

Spread the love

Ọsẹ to kọja ni wọn wọ Khalid Abdul, ẹni ọdun mọkanlelogun, wa sile-ẹjọ Majisreeti ilu Oṣogbo lori ẹsun ole jija.
Khalid ni wọn fẹsun kan pe o ji ẹrọ to maa n ṣe atunda iwe, iyẹn, Gestetner Duplicating Machine ati mansinni itẹwe meji (typewriter) eleyii to jẹ ti Alhaji Rẹmi Marindọti.
Apapọ owo awọn nnkan ti o ji ninu sọọbu ọkunrin naa lọjọ keje, oṣu kẹwaa, ọdun yii, ọhun ni wọn pe ni ẹgbẹrun lọna ojidinlẹgbẹta Naira (#560,000).
Gẹgẹ bi ASP Abiọdun Fagboyinbo to jẹ agbefọba ṣe sọ, ṣe ni Khalid fọ fẹnsi ile Alhaji Marindọti to wa lagbegbe Ido-Ọṣun, nitosi Oṣogbo, ni nnkan bii aago mọkanla aabọ alẹ, to si ji awọn nnkan naa.
Fagboyinbo ni abala ọtalenirinwo o din mẹsan-an ofin ikẹrindinlọgbọn ti iwa ọdaran tipinlẹ Ọṣun n lo ti ṣalakalẹ ijiya to tọ fun ẹni ti ọwọ ba tẹ pe o hu iru iwa ti Khalid hu naa.
Ṣugbọn Khalid, ẹni ti ko ni agbẹjọro kankan lati ṣipẹ fun un nile-ẹjọ sọ pe oun ko jẹbi ẹsun mẹtẹẹta ti wọn fi kan oun.
Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Adajọ Fatimah Sodamade faaye beeli silẹ fun olujẹjọ pẹlu ẹgbẹrun lọna ọgọrun Naira (100), ati oniduuro kan ni iye kan naa, pẹlu afikun pe oniduuro naa gbọdọ ni ẹri pe o san owo-ori fun odidi ọdun mẹta.
Lẹyin naa lo sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kejilelogun, oṣu kẹwaa, ọdun yii.

(1)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.