Ọwọ tẹ Francis, amofin to n ba ọkunrin ẹgbẹ rẹ laṣepọ

Spread the love

Ahaamọ ni adajọ paṣẹ pe ki lya kan, Francis Ikebudi, ti wọn fẹsun kan pe o maa n ba awọn ọkunrin ẹgbẹ rẹ laṣepọ niluu Ilọrin ṣi wa, lẹyin ti Adajọ AbdulGaniyu Ajia to gbọ ẹjọ rẹ sun un siwaju.

Iwadii fi han pe ọlọkada kan to gbiyanju lati ba laṣepọ, Peter John, lo fi iṣẹlẹ naa to ileeṣẹ ọlọpaa leti.

Wọn ni afurasi yii pe ọlọkada ọhun lati gbe e lọ sile. Lasiko ti wọn n lọ lọna, Francis ṣeleri lati ran ọkunrin ọlọkada naa lọwọ. O ni ko waa mọ ile oun. Lẹyin tiyẹn gbe e dele lo gba nọmba rẹ,to si bẹrẹ si i pe e ni gbogbo igba.

Lara ileri to ṣe ni pe oun maa fun un ni miliọnu kan Naira, oun tun maa ba a kọ idanwo WAEC ati JAMB to ba gba lati ba oun laṣepọ. 

Bi wọn ṣe dele ni Francis ni kiyẹn wọle wa. Nigba ti wọn wa ninu ile lo bẹrẹ si i fọwọ pa ọkunrin naa lara.

Iyalẹnu lo jẹ fun ọlọkada naa nitori ko ri iru ẹ ri. Lọgan lo fi ọgbọn ṣe e, to si bẹ Francis lati jẹ koun lọ sile, koun pada wa.

Kete to kuro nibẹ lo sare gba agọ ọlọpaa lọ lati fi to wọn leti. Awọn ọlọpaa tẹle e de ile naa, wọn si farapamọ si agbegbe yii.

Bi ọlọkada naa ṣe wọle ni Francis bẹrẹ si i ṣe bii iṣe rẹ, ko too di pe o ki ọkunrin naa mọlẹ lawọn ọlọpaa ti ya bo inu ile naa.

Bi wọn ṣe wọle ni wọn ba awọtẹlẹ lasan nidii Francis. Kinni rẹ ti le tandi, o si fi ipara Vaseline pa a ni imurasilẹ lati ki i wọ oju idi John. Iyooku ipara to lo naa wa lori bẹẹdi rẹ.

Agbẹjọro ijọba, Toyin Ọlaṣupọ, tako beeli afurasi naa. O rọ ile-ẹjọ lati fi i pamọ sahaamọ ọgba ẹwọn. Ṣugbọn agbẹjọro olujẹjọ, Angus Ibebukwe, tako o, o rọ adajọ lati gba beeli ọkunrin naa.

Francis lọwọ tẹ lagbegbe Fate/Tankẹ lọsẹ to kọja nihooho ọmọluabi, lasiko to n sa fawọn ọlọpaa. 

Wọn lo ti n ba awọn ọkunrin laṣepọ tipẹ, eyi to gbiyanju lati ṣe ni ti ọlọkada to pada ko o si wahala yii.

Niṣe ni wọn ni Francis bẹ sita, to si fọwọ bo kinni rẹ lasiko tawọn agbofinro n le e, ko too di pe ọwọ wọn tẹ ẹ.

Awọn to n gbe agbegbe ile Francis ṣalaye pe ki i ṣe akọkọ rẹ ree, wọn ni ọ̣pọlọpọ ọdọmọkunrin ni wọn ti ko si pampẹ rẹ.

Wọn ni awọn ti fọrọ rẹ to ileeṣẹ ọlọpaa leti ri ṣugbọn lọna kan tabi omiiran wọn pada yọnda rẹ ti wọn si yanju ọrọ naa. Eleyii to ṣe gbẹyin yii lawọn gbagbọ pe o ṣe tẹ.

(18)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.