Ọwọ tẹ ero inu ọkọ to fẹẹ ja takisi gba l’Ekoo, ibọn iṣere ọmọde lo lo

Spread the love

Ọwọ ti tẹ afurasi ọdaran kan, Ogundoju Ọlalekan, fun ẹsun idigunjale. Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, CSP Chike Oti, lo sọ eleyii di mimọ ninu atẹjade to fi ṣọwọ si akọroyin wa lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii. Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye, o ni ni nnkan bii aago mejila ku iṣeju mẹwaa oru Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja ni ọga ọlọpaa teṣan Maroko, CSP Isah Abdulmajid, ko awọn ọmọ rẹ lẹyin, lasiko ti wọn si n ṣọde kiri ni wọn ri ọkunrin kan, Ogadinma Ikeagu, ẹni to n wa ẹkun mu bii gaari. Ikeagu ṣalaye fawọn agbofinro yii pe ṣe ni awọn ero meji toun fi ọkọ ayọkẹle Toyota Corrolla toun fi n ṣe takisi, eyi ti nọmba rẹ jẹ KA 69 FE, gbe ja ọkọ naa gba mọ oun lọwọ laduugbo African Shrine, ti oun ti gbe wọn.

Lẹsẹkẹsẹ ni ọga ọlọpaa naa ni ki Ikeagu ma wulẹ sunkun rara, ko wọ inu ọkọ awọn, wọn si tọpasẹ awọn ole naa lọ. Adugbo Victoria Island, ni wọn ti le ọkọ naa ba. Lẹsẹkẹsẹ ni ọkan ninu awọn ole naa bẹ silẹ, to si sa lọ, ṣugbọn ọwọ pada tẹ Ogundoju Ọlalekan, ẹni to ni Ojule Kẹrinla, adugbo Shomorin, Ifakọ Gbagada, loun n gbe.

Lasiko ti wọn n yẹ ara rẹ wo ni wọn ba igi to ṣe bii ibọn lọwọ rẹ, ko si fi akoko awọn ọlọpaa ṣofo to fi jẹwọ pe oun mọ nipa iwa ọdaran naa.

Otti ni Kọmisanna ọlọpaa nipinlẹ Eko, Imohimi Edgal, ti paṣẹ pe kawọn wa ẹni keji Ọlalekan ri, kawọn si ko awọn mejeeji lọ si kootu lati lọọ jẹjọ ẹsun idigunjale.

 

(9)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.