Ọwọ tẹ Dayọ atawọn meji mi-in nibi ti wọn ti n ji waya ina ka n’Ilajẹ

Spread the love

Awọn ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti fi panpẹ ọba gbe awọn afurasi mẹta kan, Dayọ Babatunde, Isaac Odiwiri ati Kunle Okuyiga,  ti wọn n ji waya ina ijọba ka lagbegbe Ilajẹ.

 

Awọn afurasi ọhun lọwọ tẹ niluu Ode-Etikan, nijọba ibilẹ Ilajẹ, ni nnkan bii aago meji ọsan ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja lọhun-un.

 

Awọn kan la gbọ pe wọn ka awọn tọwọ tẹ ọhun mọ ibi ti wọn ti n ji awọn waya naa ka lori ẹrọ tiransifọma tuntun ti wọn ṣẹṣẹ ri siluu Ode-Etikan, lọsan-an ọjọ yii.

 

Bi wọn ṣe taju kan-an ri awọn to ti n sọ wọn tẹlẹ lawọn gbewiri ọhun fa ibọn yọ, ti wọn si n yin in soke kikan kikan lati le awọn eeyan yii sẹyin, ki wọn ma baa ri wọn mu.

 

Loootọ lawọn afurasi naa kọkọ sa lọ, ṣugbọn ko pẹ pupọ tawọn araalu to n lepa wọn fi ri wọn mu, ti wọn si fa wọn le ọlọpaa lọwọ.

 

Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Fẹmi Joseph, fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, o sọ fun wa pe ikawọ Isaac Odiwiri ni wọn ti pada ba ibọn agbelẹrọ nla kan ti wọn fi n ṣiṣẹ ibi wọn.

 

Awọn ẹru ofin mi-in to ni wọn tun ba nikaawọ wọn ni irin nla kan ti wọn fi n ja geeti ibi ti wọn ba gbe ẹrọ amunawa si, waya loriṣiiriṣii ati ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Carina kan.

 

O ni awọn tọwọ tẹ naa ti jẹwọ pe loootọ ni ẹsun ti wọn fi kan awọn. Joseph ni gbogbo akitiyan ni awọn ọlọpaa n sa lati ri awọn ẹgbẹ wọn ti wọn ti sa lọ mu, kawọn naa le foju wina ofin.

 

Ni kete ti iwadii ba ti pari lori ẹsun ti wọn fi kan awọn afurasi naa lo ni wọn yoo foju ba ile-ẹjọ.

 

 

 

(0)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.