Ọwọ tẹ Dauda fẹsun idigunjale l’Ekoo

Spread the love

Awọn ọlọpaa ayaraṣaṣa (RRS), ti ipinlẹ Eko, ti mu Dauda Moruf, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn, ati ekeji rẹ ti wọn forukọ bo laṣiiri, ti wọn lo ṣẹṣẹ ti ẹwọn de ni fun ẹsun idigunjale. Adugbo Cement Bus stop, to wa ni titi Marosẹ Eko si Abẹokuta lọwọ ti tẹ wọn, bo tilẹ jẹ pe Oshodi ni awọn afurasi naa ni awọn n lọ nirọlẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ to kọja. Ọrọ ti Dauda sọ ni awọn ọlọpaa fi tẹsẹ bọ iwadii, tọwọ si tẹ Mubara Afeez, ẹni ọdun marundinlọgbọn ati Emmanuel Adeshina, ẹni ọdun mejidinlọgbọn ti awọn pẹlu Dauda jọ maa n ṣiṣẹ.

Ibọn ilewọ dudu kan to jẹ iṣere ọmọde ati ibọn gidi kan ni wọn ba lọwọ wọn.

Afurasi ole mi-in ti wọn tun mu laduugbo Pen Cinema lasiko toun pẹlu awọn ẹgbẹ rẹ n ja awọn ero inu ọkọ lole lọna to lọ si Iju si Ishaga, ti wọn si ba ibọn ilewọ kan lọwọ rẹ ni Ọlamide Bello.

 

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.