Ọwọ tẹ ayederu ọtẹlẹmuyẹ l’Oṣogbo, lo ba ni wahala Ọfa/Erinle lo sọ oun di onirọ

Spread the love

Ileeṣẹ ajọ ọtẹlẹmuyẹ, Department of State Services, ẹka tipinlẹ Ọṣun ti ṣafihan baba agba kan, Ademọla Festus Adelabu, lori ẹsun pe o n lu awọn araalu ni jibiti pẹlu ileri pe oun yoo ba wọn waṣẹ si ajọ naa.

 

Igbakeji ọga-agba nileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ la gbọ pe baba ẹni ọdun mejilelọgota yii n pe ara rẹ fawọn ti wọn n ko sọwọ ẹ, koda, ile nla lo kọ siluu Emure Ekiti lati ara owo to n gba lọwọ awọn araalu.

 

Gẹgẹ bi ọga agba ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ tipinlẹ Ọṣun to ṣafihan Adelabu ṣe sọ, eeyan bii mẹẹẹdogun lakọsilẹ rẹ wa gbangba pe baba yii ti lu ni jibiti, o si ti gba to miliọnu mẹta ati diẹ Naira (N3.150 million), lọwọ awọn mẹjọ lara awọn to lu ni jibiti.

 

Ogunjọ, oṣu kejila, ọdun to kọja, la gbọ pe ọwọ tẹ Adelabu, ẹni to ti figba kan ṣiṣẹ nileeṣẹ to n pese ina nilẹ wa, iyẹn National Electric Power Authority ko too di pe o kuro nibẹ lọdun 2012, lasiko to tun fẹẹ gba owo lọwọ ẹlomi-in to fẹẹ lu ni jibiti.

 

Sinkun lo ko sọwọ awọn ikọ Special Incident Response Team of the**** niluu Owode-Ẹdẹ lọjọ naa. A gbọ pe ọmọ bibi ipinlẹ Ọṣun mẹjọ wa lara awọn to lu ni jibiti, o faye han eeyan meji l’Ondo, mẹta nipinlẹ Ọyọ ati ẹni kan nipinlẹ Kwara.

 

Nigba ti n dahun ibeere awọn oniroyin, Adelabu ni bi eto ọrọ-aje orileede yoo ṣe dẹnukọlẹ lo fa a ti oun fi dẹni to n parọ jẹun.

 

Gẹgẹ bo ṣe wi, “ka-ra-ka-ta ni mo n ṣe tẹlẹ pẹlu owo ifẹyinti mi, mo n ta irẹsi, bẹẹ ni mo n ta bata, ṣugbọn wọn jo sọọbu mi to wa lagbegbe Sannu Abba, lasiko wahala Offa/Ẹrinle.

 

“Mo ko lọ siluu Ibadan, mo si bẹrẹ owo ṣiṣe pada, lọjọ kan, mo lọọ raja, mo wa n dari bọ, nigba ti a de Ṣaki, awọn aṣọbode fẹẹ gbẹsẹ le ọja mi, kia lẹmi kan sọ fun mi pe ki n pe ara mi loṣiṣẹ ajọ ọtẹlẹmuyẹ, bi mo ṣe sọ bẹẹ ni wọn ni ki n maa lọ.

 

“Latigba naa ni mo ti n pe ara mi bẹẹ. Iyawo mẹta ni mo fẹ, ṣugbọn ọkan ti ku ninu wọn, bẹẹ ni mo bimọ to pọ, koda, mẹta ninu wọn ni wọn ṣi jẹ arobo.

 

“Mo rọ ajọ ọtẹlẹmuyẹ lati ṣiju aanu wo mi, ki wọn dariji mi, mo si ṣeleri pe ti mo ba le bọ ninu eleyii, ma a yipada patapata kuro ninu iru iwa bayii.”

Laipẹ yii ni Adelabu yoo foju bale-ẹjọ gẹgẹ bi ọga agba ajọ DSS l’Ọṣun ṣe sọ, ko baa le jẹ arikọgbọn fun gbogbo awọn ti wọn ba n hu iru iwa bẹẹ, tabi awọn ti wọn le maa gbero nnkan bẹẹ lọkan.

 

(9)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.