Ọwọ tẹ awọn ayederu agunbanirọ nipinlẹ Kwara

Spread the love

Stephen Ajagbe

Awọn mẹrin kan ti wọn gbọna ẹburu waa sinru ilu nipa lilo ayederu iwe, lọwọ palaba wọn ti ṣegi lọsẹ to kọja ni ipagọ awọn agunbanirọ to wa ni Yikpata, nipinlẹ Kwara.

Awọn akẹkọọ naa, Eziem Francisca, Igbo Hilary, Amaechi Kisito Chima, ati Duru Ifeanyi, lọwọ tẹ lasiko tawọn alakooso eto isinru agunbanirọ naa n ṣayẹwo fawọn agunbanirọ isọri keji ti wọn pin sipinlẹ naa lati waa sin ilẹ baba wọn.

Kete tọwọ ba wọn ni wọn fa wọn le ọlọpaa lọwọ lati gbe igbesẹ to ba yẹ lori ọrọ wọn.

Lọsẹ to kọja yii ni ajọ NYSC ko wọn lọ sile-ẹjọ Majisreeti ilu Ilọrin lati lọọ ṣalaye ohun ti wọn ri ti wọn fi gbe iru igbesẹ bẹẹ.

Ọga agba to n ṣakoso ipagọ ọhun lo kọwe si kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Kwara lati fi iṣẹlẹ naa to o leti. Ninu iwe-ẹsun to kọ ranṣẹ lo ti ṣalaye pe ọna ẹburu pẹlu lilo ayederu iwe lawọn afurasi mẹrẹẹrin fi gbe ara wọn de ipagọ naa.

Ẹka to n ṣewadii iwa ọdaran ni olu ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe gbogbo awọn afurasi mẹrẹẹrin naa ni wọn jẹwọ pe loootọ lawọn gba awọn ayederu iwe lati le kopa ninu eto agunbanirọ naa.

Wọn ni ki i ṣe pe o kan wu awọn lati ṣe ohun tawọn ṣe naa, ṣugbọn bawọn ko ṣe lanfaani lati kẹkọọ yege pẹlu awọn ẹgbẹ awọn ni fasiti ipinlẹ Imo to wa niluu Owerri, lo sun awọn debi tawọn fi gbero lati da a bii ọgbọn wo.

Akọsilẹ ileeṣẹ ọlọpaa fihan pe aifoju si ẹkọ, aidangajia lẹnu ẹkọ wọn ati bi wọn ko ṣe le yanju gbogbo iṣoro to ba wọn ninu ẹkọ wọn lo mu wọn fẹẹ fi ọna jibiti gba iwe-ẹri agunbanirọ ni dandan. 

Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn yoo sapa lati ri i pe ọwọ tẹ awọn to ba wọn ṣe gbogbo ayederu iwe ti wọn lo ti wọn fi de ilẹ ipagọ awọn agunbanirọ naa.

Ẹsun ta a fi kan wọn ni pe wọn ko kunju oṣuwọn labẹ ofin lati kopa ninu eto isinlu, ati pe won ṣe ayederu iwe, wọn si fẹẹ tan ijọba jẹ.

Ṣaaju ni Adajọ Ibrahim tile-ẹjọ Magisreeti ti ni ki wọn ṣi wa lahaamọ ileeṣẹ ọlọpaa.

Ọsẹ yii nireti wa pe igbẹjọ yoo bẹrẹ lori ẹsun ti wọn fi kan wọn. 

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.