Ọwọ tẹ awọn afurasi ajinigbe meje l’Ondo

Spread the love

Ko din lawọn afurasi bii meje tọwọ tẹ lọsẹ to kọja yii lasiko ti awọn ṣọja ati ọlọpaa nipinlẹ Ondo n wa gbogbo inu igbo tawọn ajinigbe ọhun fi n boju ṣiṣẹ ibi wọn.

 

Alukoro awọn, ṣọja, Ọgagun Ojo Adelẹgan, fidi rẹ mulẹ pe awọn ṣọja lo kọkọ bẹrẹ igbesẹ naa pẹlu bi wọn ṣe fi odidi ọjọ mẹta fọ awọn igbo to wa ni ayika Ọwọ si Ose-Ọba Akoko.

 

Awọn agbegbe yii ni Adelẹgan sọ pe awọn oniṣẹẹbi ọhun ti maa n ji awọn eeyan gbe, ti wọn si tun n fipa ba awọn mi-in lo pọ lẹyin ti wọn ba ti gbowo ọwọ wọn tan.

 

Awọn afurasi mẹta la gbọ pe ọwọ awọn ṣọja ọhun tẹ laarin Ọjọbọ, Tọsidee,  siọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja lọ lọhun-un ti wọn fi ṣeto ọhun, ti wọn si tun dana sun ọpọlọpọ ahere tawọn oniṣẹẹbi naa kọ sinu igbo.

 

Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja yii ni igbakeji kọmisanna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Mudasiru Abdulahi, ṣaaju awọn oṣiṣẹ wọn to n lọ si bii aadọrun-un, ti wọn si mori le inu igbo nla to wa lagbegbe Ose Ọba Akoko lati ṣawari awọn ajinigbe to n ṣọṣẹ loju ọna Ọwọ si Ikarẹ.

 

Nnkan bii aago mẹfa aabọ aarọ ni wọn ji de Ọba Akoko, ti wọn si pin ara wọn sọna mẹta ọtọọtọ ki wọn too wọnu igbo naa lọ.

 

Isọri awọn ọlọpaa kan kọju si ọna Ọwọ pada, awọn mi-in kọju si Ikarẹ Akoko,nigba tawọn isọri kẹta wa laarin wọn, ti wọn si jọ fọ gbogbo inu aginju ọhun fun odidi wakati mẹrin gbako.

 

Larin asiko yii ni wọn fi panpẹ ọba gbe baba agbalagba kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Jahae Muhammed ati Jimoh Ahmed.

 

Jahae tọwọ tẹ yii ni wọn juwe gẹgẹ bii agbodegba fawọn ajinigbe to n ṣọṣẹ ni gbogbo agbegbe naa, ọjọ pẹ diẹ ti wọn si ti n wa a latari bi awọn afurasi kan tọwọ tẹ ṣaaju ṣe n darukọ rẹ gẹgẹ bii baba isalẹ awọn.

 

Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun wa, alukoro awọn ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Fẹmi Joseph, ni ọpọlọpọ awọn nnkan ija oloro, aṣọ, bata atawọn ẹru mi-in ti wọn fura si pe awọn oniṣẹẹbi naa fipa gba lọwọ awọn ti wọn ji gbe ni wọn ba ni ikawọ awọn meji tọwọ tẹ ọhun.

 

Ọpọlọpọ awọn ajinigbe naa ti wọn raaye sa lọ  ni awọn ọlọpaa ṣi n wa, nigba ti iwadii ṣi n tẹsiwaju lori ọrọ awọn ti wọn ri mu.

 

Alukoro ọhun sọ fun wa pe eyi ti wọn ṣe lọsẹ to kọja yii ni yoo jẹ igba keji ninu oṣu to kọja yii ti awọn yoo lọọ gbe ija ka awọn ajinigbe mọ inu igbo, nibi ti wọn ti n ṣiṣẹ ibi wọn.

 

O ni lọjọ kẹjọ, oṣu to kọja, ni kọmisanna awọn, Olugbenga Adeyanju, ṣaaju awọn ọlọpaa kan lọ sinu igbo nla Amorin, to wa lagbegbe Uso, nitosi Ọwọ,nibi ti wọn ti doju ija kọ awọn ajinigbe, ti wọn si mu ọkan balẹ ninu wọn, ti pupọ lara awọn to sa lọ si fara gbọta.

 

Ni idaji ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kan naa, lo lawọn ajinigbe tun ya bo inu Ẹsiteeti Shagari, l’Akurẹ, nibi ti wọn ti ji awọn eeyan meji, Alaaji Suleiman Ibrahim ati Moshood Suleiman, gbe.

 

Gbogbo awọn ẹṣọ alaabo to wa nipinlẹ Ondo ni wọn tete dide sọrọ naa, ti wọn si ja fitafita la ti ri awọn ti wọn ji gbe naa gba lọwọ wọn niluu kan ti wọn n pe ni Ìjẹ̀lú, lẹgbẹẹ Ọwọ.

 

Meji ninu awọn ajinigbe ọhun, Alhassan Saleh, ẹni ọdun mejilelogoji ati Yahaya Yakubu, ẹni ọdun mẹrinlelogun ni wọn fi panpẹ ọba gbe nigba tawọn yooku si raaye sa mọ awọn ọlọpaa lọwọ.

 

 

(5)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.