Ọwọ ọlọpaa ti tẹ afurasi kan lori akẹkọọ ti wọn yinbọn pa l’Ọwọ

Spread the love

L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja, ni ọwọ ọlọpaa ipinlẹ Ondo tẹ ọkan ninu awọn afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun to yinbọn pa akẹkọọ Poli Ọwọ ti wọn pe orukọ rẹ ni Ajibade.

 

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Fẹmi Joseph, to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun wa sọ pe lojiji lawọn eeyan to wa lagbegbe Poli ọhun bẹrẹ si i gbọ iro ibọn lọjọ iṣẹlẹ yii, eyi to ṣokunfa bi awọn agbofinro kan lati teṣan ‘B Difiṣan’, niluu Ọwọ, labẹ idari SP Onigbinde sare lọ si agbegbe ọhun lati mọ ohun to n ṣẹlẹ.

Awọn ọmọ ẹgbe okunkun kan ni wọn ṣina ibọn bolẹ niwaju geeti Poli Ọwọ, ni nnkan bii aago mẹfa irọlẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja. Asiko naa ni wọn yinbọn pa Ajibade to wa ni ipele kin-in-ni ni poli ọhun lasiko to fẹẹ lọ ra nnkan ti yoo jẹ.

Oku ọmọkunrin ọhun nikan lo ni awọn agbofinro ba nibi ti wọn pa a si, leyii to mu ki wọn fura pe o ṣee ṣe ko jẹ awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun kan lo ṣiṣẹ ibi naa.

 

Lẹyin o rẹyin ni ọwọ pada tẹ ẹnikan ti wọn fura si pe o mọ nipa ohun to ṣẹlẹ naa, ẹni to ni o ṣi wa ni akata awọn, o si ti n sọ gbogbo ohun to mọ lori ọrọ iku oloogbe naa.

 

Fẹmi ni ọwọ ko ni i pẹẹ tẹ gbogbo awọn afurasi to lọwọ ninu iṣẹ ibi naa, ti wọn yoo si ko wọn lọ sile-ẹjọ lati lọọ foju wina ofin.

 

Ọpọlọpọ awọn to ba wa sọrọ nipa iṣẹlẹ yii ni wọn ko le fidi rẹ mulẹ fun wa boya akẹkọọ ti wọn pa ọhun wa lara awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun tabi bẹẹ kọ.

 

(5)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.