ỌWỌ ỌLỌPAA TẸ YAHAYA TO MAA N ṢE AYEDERU OWO NILỌRIN

Spread the love

Ọwọ ajọ ti n gbogun ti iwa idigunjale (F-SARS) nipinlẹ Kwara ti tẹ afurasi ọdaran kan, Yakubu Yahaya latari pe wọn ka ayederu owo ẹgbẹrun kan naira lọwọ rẹ loriṣiiriṣii. Yahaya, ọmọ bibi ilu Auchi, nipinlẹ Edo ni wọn nawọ gan, ti wọn si ka oriṣiiriṣii ẹgbẹrun kan naira to jẹ feeki mọ ọn lọwọ. Gẹgẹ bi ọlọpaa kan to ṣofofo ọrọ yii fun ALAROYE ṣe sọ, wọn ni niṣe ni afurasi naa ati awọn eeyan ti n ko owo ayederu owo naa kaakiri ilu Ilọrin. Aṣiri wọn tu nigba ti Yahay fẹ fi owo ayederu naa ra eso lọwọ obinrin kan ti wọn p’orukọ rẹ ni Khadija. Nigba ti obinrin naa ri pe ayederu lowo naa lo fi igbe bọnu, eyi ti o si mu ki awọn eeyan nawọ gan Yahaya, ti ekeji rẹ si sa lọ. Yahaya jẹwọ pe loootọ loun maa n ko ayederu owo kiri lasiko ti awọn ọlọpaa n fi ọrọ po o nifun pọ, pẹlu alaye pe iṣẹ toun maa n ṣe ni ayederu owo ni ṣiṣe. O ni fẹrẹ to milionu metadinlogoji toun ti ṣe jade ni ayederu latigba toun ti bẹrẹ owo naa.
Ṣa, SP Ajayi Ọkasnmi to jẹ alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara loun ko ti i gbọ nipa iṣẹlẹ naa, ṣugbọn o ṣeleri lati kan si akọroyin wa pada.

(28)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.