Ọwọ ọlọpaa tẹ ogboloogbo adigunjale l’Ejigbo

Spread the love

Ọwọ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti tẹ afurasi adigunjale kan ti wọn ti n wa lọjọ to ti pẹ, Ṣẹgun Kazeem, ti inagijẹ rẹ n jẹ ‘No Case’. Gẹgẹ bi awọn ọlọpaa ṣe sọ, wọn ni ọkunrin naa pẹlu awọn yooku rẹ lo maa n yọ awọn ara agbegbe Ejigbo, niluu Eko, lẹnu. Ṣẹgun, ẹni ti wọn lo tun jẹ ọkan gboogi ninu awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹyẹ ni ọwọ ba nigba ti ọga agba ni teṣan ọlọpaa to wa ni Ejigbo, CSP Ọlabisi Okuwọbi, lewaju awọn ọlọpaa yooku lọọ mu ọkunrin naa.

Ṣaaju ọjọ ti wọn mu un yii ni ọwọ ti tẹ aburo rẹ kan, Fẹmi Kazeem, lasiko to fẹẹ ja obinrin kan lole. Nigba ti ọwọ tẹ Fẹmi lo darukọ ẹgbọn rẹ. Inu ọgba ileewe girama kan ni ọwọ ti tẹ Ṣẹgun, nibi to ti fẹẹ ja maṣinni ti wọn fi maa n yẹ kaadi idibo wo (PVC Machine) gba.

Gbogbo akitiyan wa lati ri alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ba sọrọ ka le fidi iroyin yii mulẹ lo ja si pabo, nitori ko gbe ipe wa ni gbogbo igba ti a n pe e.ni

(61)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.