Ọwọ ọlọpaa tẹ ayederu ṣọja ati afurasi adigunjale kan l’Ekoo

Spread the love

Aduugbo Mobọlaji Bank Anthony, to wa nitosi papakọ ofurufu Muritala Muhammed, Ikẹja, lawọn ọlọpaa ayaraṣaṣa (RRS), ti mu ayederu ṣọja kan, Yusuf Quadri, ẹni ọdun mejilelogun, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja. Bẹẹ ni wọn si mu afurasi adigunjale kan nibi to ti n ja awọn ero inu ọkọ lole l’Oṣhodi. Yusuf, ọmọ bibi ipinlẹ Ogun, lọwọ tẹ nigba ti awọn ọlọpaa da a duro nibi to ti n wa kẹkẹ Maruwa lọ lagbegbe Airport Road, eyi ti ijọba ipinlẹ Eko si ti fofin de pe ẹnikẹni ko gbọdọ wa kẹkẹ lọna ibẹ. Nigba ti wọn da a duro, ṣe lo ni ṣọja loun, ibeere ti awọn agbofinro si bi i lo tu aṣiri rẹ pe ṣe opurọ ni, ki i ṣe ṣọja rara.

Quadri, ẹni to ni oun niwee ẹri mẹfa, jẹwọ pe oun ji aṣọ iṣẹ ọga ṣọja kan ti wọn ṣẹṣẹ fun nigbega lasiko toun n ran an lọwọ lati palẹ ẹru rẹ mọ ni. O ni lẹyin toun ji i mu tan loun lọọ fi ya fọto, eyi toun fi ṣe kaadi idanimọ. O ṣalaye pe kaadi naa loun fi maa n tan awọn oṣiṣẹ alaabo gbogbo jẹ pẹlu awọn LASTMA, ni gbogbo asiko ti wọn ba fẹẹ mu oun.

Bakan naa, ni wọn tun mu Emeka Ohiaeri, ẹsun idigunjale ni wọn mu un fun. Wọn ni ọmọkunrin ọmọ bibi ipinlẹ Imo naa ja foonu gba lọwọ kọpa kan lagbegbe Oṣhodi. Emeka o mọ pe awọn RRS wa nitosi ti wọn n ṣọ oun, awọn ni wọn si tọpasẹ rẹ de ibi ti oun pẹlu awọn yooku rẹ sa pamọ si. Wọn ri foonu naa gba pada lọwọ rẹ, wọn si ti gbe e lọ si ọdọ ọọfiisi wọn wa ninu Ikẹja.

Nigba to n jẹwọ fun wọn, o ni foonu toun maa n ji naa loun fi maa n gbọ bukaata oun, bẹẹ oun ti ni awọn onibaara to maa n ra a lọwọ oun.

Zubair Muazu to jẹ kọmisanna ọlọpaa nipinlẹ Eko ti ni ki wọn maa gbe Emeka lọ si Panti, Yaba, nibẹ ni yoo si ti le ṣalaye awọn iṣẹ to ti ṣe l’Oṣhodi daadaa fun awọn ọtẹlẹmuyẹ.

(43)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.