Ọwọ ba Pasitọ to pa ale ẹ to si sin ageku rẹ sinu ṣọọṣi.

Spread the love

Ọwọ awọn ọlọpaa ti ba Pasitọ Oluwatobilọla Ipense ti Holy Gathering Evangelical Church Of God to wa ni Papanlato, lagbegbe ijọba ibilẹ Ewekoro nipinlẹ Ogun lanaa.

Ẹṣẹ ta a gbọ pe Oluwatobilọla ṣẹ ni pe, o ge ori ati apa ololufẹ ikọkọ rẹ, Raliat Sanni, o si sin ageku rẹ sinu ọkan lara awọn yara to sunmọ ibi pẹpẹ alagba (Altar) ṣọọṣi ẹ.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ ogun, Ahmed Iliyasu, to dari awọn oniroyin ati ọpọlọpọ awọn aladuugbo lọ sibi iṣẹlẹ naa royin rẹ bii eyi to buru jai. O ni ẹgbọn Raliat Sanni, Adebọla Saheed, lo wa sọdọ awọn ọlọpaa pe oun ko ri aburo oun lati ọjọ kọkanlelogun oṣu kẹta ọdun yii to ti jade.

Iliyasu ni nibi ifọrọwanilẹnuwo tawọn ṣe fun Oluwatobilọla, o jẹwọ pe oun loun pa Raliat Sanni loootọ, o si darukọ Pasitọ mi-in ti wọn dijọ lọwọ si ọrọ naa, iyẹn Pasitọ David Sopeju ti Iyana Egbado.

Ninu ọrọ ti Oluwatobilọla sọ fun awọn oniroyin lo ti ni oun kọ loun pa Raliat, Sopeju gan-an lo pa a, wọn fẹẹ fa oun wọ inu ẹgbẹ okunkun pẹlu tipatipa ni lọjọ ti wọn pa ọmọbinrin naa sọdọ oun.

Sopeju naa ni ọrọ ko ri bẹẹ, amọ ṣọọṣi kerubu kan naa lawọn jọ n lọ loootọ. Ọga ọlọpaa ti ni ki wọn gbe ẹjọ wọn lọ si koot

 

(57)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.