Ọwọ awọn oṣiṣẹ alaabo ipinlẹ Eko tẹ adigunjale to n fi minirasi onike boju l’Oṣodi.

Spread the love

Ọwọ awọn oṣiṣẹ alaabo (Task Force) ipinlẹ Eko tẹ Oluwọle Kayọde, ọmọ ọdun mẹtadinlogun to n ta minirasi onike fi boju gẹgẹ bi adigunjale lori afara Oṣodi.

A ri i gbọ pe awọn oṣiṣẹ alaabo mu Kayọde lẹyin to fọ gilaasi ilẹkun mọto Toyota Corolla laaye awakọ, ti o si ko foonu meji ati baagi to kun fun awọn ohun alumọni olowo-iyebiye.

Ṣiamaanu awọn oṣiṣẹ alaabo naa, Ọlayinka Ẹgbẹyẹmi, ṣalaye fawọn oniroyin pe awọn pe obinrin to lẹru lori foonu pe ko waa gba awọn ẹru rẹ ni ọfiisi awọn Task Force, Bọlade, l’Oṣodi.

Kayọde, ọmọ bibi ilu Abẹokuta naa jẹwọ pe adigunjale loun loootọ, oun ko si ṣẹṣẹ wa lẹnu ẹ. Awọn miniraasi onike toun maa n gbe kiri yii loun fi n boju ki awọn eeyan le ro pe oun fẹẹ taja fun wọn ninu sunkẹẹrẹ-fakẹẹrẹ ọkọ ni, nigba toun ba de ọdọ wọn tan loun yoo halẹ mọ wọn pe ki wọn ko ohun ini wọn wa, bi wọn ko ba si gba lati ṣe bẹẹ, oun maa n fi hama fọ gilaasi mọto wọn, bẹẹ loun ṣe ti oun fi ko ẹru arabinrin yii.

Kọmiṣanna ọlọpaa, Edgal Imohimi ti ni ki wọn gbe e lọ sile-ẹjọ

.

(4)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.