Oto ni Fulani, oto ni Hausa o

Spread the love

Ohun kan lo n ba mi leru bayii. Iyen naa ni pe kin ni yoo sele sawon omo tiwa ni Naijiria, ati awon omo tiwon, leyin ti awa ba ti lo tan. Ninu awon ti won n te atejise si mi, awon kookan ti won fe ki Buhari tun sejoba leekeji, ohun ti won ni awon fi n ronu bee ni pe bi a ko ba je ki Buhari sejoba ni 2019, ti omo Hausa mi-in ba tun gba a, o le so pe oun yoo tun lo odun mejo mi-in, iyen yoo si je odun mejila gedegbe ti awon Hausa ti lo, eleyii yoo si mu isoro ba awon eya to ku ni Naijiria yii. Iru eleyii ko le sele rara, n ko si fe ki e ronu bee. Eyi to se pataki ju bayii ni lati ronu pe nje Naijiria yoo ṣi wa ti Buhari ba tun lo odun merin mi-in gege bii olori wa. Mo fee so fun yin pe o see se ki Naijiria yii ma si mo bi Buhari ba se odun merin si i. Bi Naijiria ba si wa, o see se ka wa ninu ogun abele, tabi ka ti fonka yeleyele.
Yoo ri bee. Ki enikan ma jokoo sibi kan ko so pe Naijiria ko le tuka, tabi pe isokan yoo wa ni Naijiria. Bi isokan ba fee wa ni Naijiria, ko ni i je aye Buhari yii, ko si ni i je aye ijoba awon ti won ba n ronu bii toun. Mo ti so o tipetipe pe Buhari ti e ri yii ko ronu bii omo Naijiria, tabi bii olori Naijiria, bii omo Fulani ati okan ninu awon asaaju Fulani loun se n ronu. Bee ni mo so fun yin pe Fulani ko ronu rere si Naijiria, yato si bi Naijiria yoo ti di tiwon pata, ti won yoo fi i se ibujokoo ati orirun awon Fulani, ti gbogbo ohun to je ti Naijiria yoo je tiwon, ati epo bentiroolu ti won ni ni Naija Delta, ati owo goboi ti won n pa lati Eko, ti gbogbo re yoo bo sabe won, ti won aa na an ni ina apa, nitori apa ni won, ti won yoo si pada di omo oninaakunaa, ti won yoo bere si i pa awon eeyan agbegbe won, ti won aa ni awon n jagun esin.
Ohun ti eru se n ba mi niyen, nitori iru awon nnkan bayii, itan la fi n segun e. Bi a ba jagun, ti a lo ibon ati bombu, ti a ja titi, nigba tawon aye ba ba wa da si i pe ka pari e, itan ni won yoo beere: bawo ni lagbaja ati tamedo se je, ta lo koko de ilẹ yii, ati bee bee lo. Sugbon awon omo tiwa ko mo itan, won ko mo itan orile-ede ati orirun won. Ijoba awon Fulani mo-on-mo pa eko itan (History) re, ko ma di pe awon omo wa yoo le pa itan lola. Awon osise ijoba ti won je oga, ti won je omo Yoruba ati Ibo, ko mo eyi, won ko mo pe awon Fulani yii n lo won lasan ni, won aa fi oruko won saaju, won aa ni awon ni won gbe eto naa jade. Bee enikan wa ni koro to dabaa kinni naa fun won tele, awon aa kan maa kan ori mowee, won aa maa laagun nidii e, titi ti won aa fi gbe palapala naa jade, ti olori ijoba yoo si fowo si i.
Itan akoko ti omo Naijiria gbogbo gbodo mo ni pe awon ti won n se ijoba Naijiria ki i se Hausa, won ki i se omo Naijiria, Fulani ni won o. Aye Usman Dan Fodio ni won ro de ile yii, ogun Jihad ni won si fi kewo, ija esin ni won ni awon fee ja tabi awon waa ja, igbeyin e si ni pe won fi ara won je oba, won so ara won di olori ilu, won si le awon Hausa to ni ile won jinna sijoba ilu won, won so won di eru nipa ofa atawon nnkan ijagun buruku to wa lowo won nigba naa. Ki awon Fulani too bere ogun won ni 1804, awon Hausa ti wa ni ilu won le ni egberun odun, awon Yoruba ti wa ni adugbo won le ni egberun odun, bee si ni awon Ibo naa. Bi a ba fee jagun esin, ti a ba de ilu kan ti a si pa oba ibe nitori pe o n se keferi, sebi o ye ka fi omo oba to ba gba esin ti a mu ropo re ni, awon Fulani yii ko se bee, won so ara won di oba ni.
Mo fe ki gbogbo eni to ba fee gbo itan yii farabale daadaa o, n ko fe ki enikeni ni mo n bu Dan Fodio tabi mo n soro esin, rara o, oselu to wa ninu ohun ti awon eeyan eyin Dan Fodio se mi mo fee so, ati bi eto naa se koba wa nibi Naijiria titi doni. Se e ri i, nigba ti awon Hausa fi n sejoba won ti mo n so yii, ki i se pe ko si Fulani nile Hausa. Won wa ti won po daadaa. Sugbon darandaran ni won, won n da eran won kaakiri naa ni. Awon mi-in naa si maa n se tira, ise aafa lawon n se, bee ni won ni imo kuraani ati oro Anobi daadaa. Awon mi-in wa ti won je osise tabi eru, ti awon olowo ile Hausa n lo won ni oko tabi nibi ise itaja won. Sugbon kinni kan ni won ni, iyen naa ni pe ati eru, ati onimaalu, ati darandaran, ati aafaa, okan naa ni won ka ara awon si, eru a maa ba won, nitori alejo ati alarinkiri ni won n se.
Uthman Dan Fodio funra e, ilu Senegal ni Muhammadu ti i se baba e ti wa, awon oba Hausa si fun un nile si Gobir, nibi ti won n gbe. Nitori pe onimo loun naa, o ko awon omo re naa nimo, paapaa awon meji kan, Uthman ati aburo re, Abdullahi. Ninu awon mejeeji yii naa, Uthman ni oro esin ati imo ye julo, bo tile je pe Abdullahi naa ki se puruntu rara. Ilu Gobir, laarin awon Hausa nibe naa ni won n gbe. Leyin ti imo Uthman ti di nla lo bere si i ko awon omo ni kewu, imo kuraani, pelu eko imo ijinle, nitori o ti ko eko naa lodo awon onimo kaakiri. Gege bi a ti ri awon Hausa ti wọn n se yii, ti won ki i fee gbe aarin awon ero ati awon omo oniluu, iwa awon Hausa ko niyen, iwa awon Fulani ni. Dan Fodio ko gbe aarin ilu, Degel, abule kan nitosi Gobir. Bi awon Fulani onimaaluu, awon eru, ati awon osise ba ti lo ti won bo, odo aafa won ni won n jokoo si: Uthman Dan Fodio.
Gbogbo awon ti won n lo ti won n bo yii ni won n pada waa so fun Dan Fodio bi awon oga awon se n fiya je awon, bi won ko se n fun awon ni owo deede, bi won se n lo awon ni ilo eru ati orisiirisii awon oro ti omoose yoo so nipa oga re. Nigba ti Olorun yoo si se e, oba Gobir to je gbo nipa imo Dan Fodio, o si ni ko waa maa ko awon omo oun. Dan Fodio se bee, koda, o ko omo egbon re kan ti won n pe ni Yunfa. Leyin ti oba naa ku ni Yunfa, omo kewu Dan Fodio di oba. Ko too di igba naa, Dan Fodio ti n fi waasi bu awon oba ati alase ile Gobir, o ni esin ti won n sin ko dara, keferi ni won, nitori won ko tele suna, won n fiya je awon eru ati awon osise, won ko toju alejo ati bee bee lo. Oro yii ti bi oba to ku ninu tele, nigba ti Yunfa to je omokewu e si joba, o lodi si awon waasi ako bee. N loro ba dija, lo ba le Dan Fodio jade ni Gobiri. Ni gbo awon Fulani to n se eru ati awon to n da maalu ba tele e.
Awon yii ni won so Dan Fodio di Amiru-li-Mumini, olori awon mumini, iyen naa lo si di Emir loni-in. Awon Fulani yii ba Yunfa jagun, bee ni won kolu awon ile Hausa to ku, nitori Fulani lede ti gbogbo won n so. Lati 1804 ni won ti bere ija yii, won si ja ija naa wo 1808, nigba ti won pa Yunfa, ti won si gba gbogbo awon ilu nla nla ile Hausa. Sokoto ki i se ilu, koda, ko si lara awon ile Hausa. Kampu ni, iyen ibi ti awon Dan Fodio maa n koko duro si ki won too loo kolu ilu kan. Nigba ti won segun tan pata, ti won si so ara won di oba le awon oniluu lori ni won fi Sokoto se ibugbe won, ti won si so ibe di olu ilu Jihaadi, ti Dan Fodio si yi oruko tire pada kuro ni Emir, to di Sultan.
Kin ni kan wa ninu oro yii o. Elesin gidi ni Dan Fodio, musulumi taara, onimo to si fe igbe-aye daadaa fun gbogbo eeyan gege bi ofin Islam ti wi ni. Sugbon awon ti won tele Dan Fodio, awon onimaalu, awon eru, awon alarinkiri, awon onise-ogba, awon ti won pa awon olowo won nitori pe won ri agbara lojiji, awon ti won ji dukia awon ti won jo n sise lodo won tele ko ti won si be won lori loruko Jihadi ti won ko tete mo itumo re, ti won si pada di oba. Abi meloo ni omo Dan Fodio to di oba? Eru ati Fulani onimaalu ati awon ipanle lo so ara won di oba ni awon ile Hausa wonyi. Ohun to fa a ree to fi je lodun 1900, nigba ti Lugard yoo pada de ile Hausa lasiko ti awon oyinbo gbajoba Naijria, aburu ti awon Fulani yii n se ju ti awon ti won gbajoba lowo won lo. Pupo ninu won ko ranti kuraani ati oro Anobi mo, nigba to je eru ni iran baba won lati ibere aye wa. Nibi ti isoro wa ti bere niyen.
A o maa ba itan naa bo wẹrẹwẹrẹ.

(687)

1 Comment

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.