Ọtọ lohun to wa ninu yin, ẹ yee tan wa jẹ

Spread the love

Boya ni awọn oloṣelu ti wọn n ṣejọba Naijiria yii mọ pe ọpọlọpọ iṣẹ ti wọn n ran si awọn araalu lasiko ọdun gbogbo ko wulo kan bayii leti wọn mọ. Ko sohun meji to fa a ju pe awọn araalu ti mọ pe irọ lọpọlọpọ awọnoloṣelu yii n pa. Irọ buruku, irọ gbuu, ọrọ ti ko loootọ, ti ko si ti ọkan awọnti wọn darukọ wọn pe wọn sọ ọ jade wa ni wọn n sọ faraalu, awọn eeyan paapaa si ti jagbọn wọn. Bi ọdun kan ba ti de bayii, awọn gomina, minista aarẹ ati igbakeji rẹ, ati awọn mi-in bẹẹ ti wọn wa ni ipo oṣelu pataki lawujọyoo bẹrẹ si i sọ awọn ọrọ fawọn eeyan, pe bayii ni ki wọn ṣe, ọna yii ni ki wọn gba, iwa ti yoo jẹ ki oriire ba awọn ati Naijiria niyẹn. Ṣugbọn awọn tiwọn n sọrọ yii ki i ṣe bẹẹ, ọtọ lọna ti awọn n gba, ọtọ lohun ti wọn n ṣe.Awọn ti wọn n sọ pe ki araalu huwa bii Jesu Kristi lasiko ọdun Ajinde yii, awọn gan-an ni eṣu ọdara ti wọn ba ilẹ yii jẹ. Awọn ti wọn pe ki araalu ma jale ni ole, awọn ni wọn n ji owo ilu ko, awọn ni wọn n fi gege ba ti ọpọlọpọọmọ Naijiria jẹ nigba ti wọn ba ti ko owo to yẹ fun idẹra gbogbo ilu lọ. Awọn ti wọn n pe ki araalu ni suuru yii, awọn yii naa ni wọn n lo awọn tọọgi lati pa awọn oloṣelu ẹgbẹ wọn, ti wọn n da wahala silẹ laarin ilu, tiwọn n ṣojooro lasiko ibo, ti wọn ko si kọ iye ẹda ti ẹmi wọn le bọ junnu nitori pe awọn fẹẹ wa nipo agbara, nibi ti wọn yoo ti ri owo ko lọ. Nigba tiwọn ba ṣe gbogbo aburu yii tan, wọn yoo jade si gbangba lasiko ọdun, wọn yoo maa sọ katikati, wọn yoo maa sọ woroworo jade lẹnu. O fẹrẹ ma si oloṣelu kan ti ko ṣe waasu fun araalu lasiko ọdun Ajinde to kọja yii. Bẹẹki i ṣe araalu lo nilo iwaasu, awọn gan-an ti wọn n kiri yii ni. Awọn oloṣelu yii ni ole, awọn naa ni apaayan, awọn kan naa ni adaluru, awọn kan naani ẹni ibi. Ọrọ ti awọn n sọ lẹnu wọnyi, bi wọn ba fi idaji rẹ ṣe iwa hu, ilu yii ko ni i ri bo ti ri yii, orilẹ-ede yii yoo si dara ju bayii lọ. Kari aye bayii lorukọgbogbo ọmọ Naijiria n bajẹ, a ko jẹ ẹni apọnle, a ko jẹ ẹni-iyi nibi kan, nitori iwa ti awọn ọmọ wa n hu lẹyin odi, ati nitori iwa aburu ti wọn n gbọnipa awọn aṣaaju wa gbogbo. Bẹẹ awa ti a wa nile naa ko gbadun, oriṣiiriṣii iya lo n jẹ kaluku, amumọra naa pọ debii pe ko sẹni to le sọ pe aye oun dara bi oun ṣe fẹ gan-an ni Naijiria yii, afi awọn ole ti wọn ri owoilu ji ko, awọn oloṣelu onimọnaafiki ti wọn n ko owo ijọba jẹ. Nitori bẹẹ, ki gbogbo yin lọọ mọ pe araalu o nilo iwaasu ati waasi ẹyin oloṣelu wọnyi,ẹtọ ni wọn n beere lọwọ yin pe ki ẹ ṣe. Ẹyin gan-an ni ki ẹ waasu funra yin, ẹ ba ara yin sọrọ, ki ẹ ṣe ohun to dara loju araalu ati loju Ọlọrun. Ẹfẹjọ silẹ, ẹ jọọ, ko saraalu to fẹẹ gbọrọ ẹnu yin, wọn ti mọ pe o-jale-onile-bo-tiẹ-lẹyin ni oloṣelu Naijiria, awọn ti wọn n ba tọmọ araaye jẹ fi tun tiwọnṣe. Ọjọ n bọ o, oluwa n bọ waa dajọ afeyinpinran to loun o jẹ nibẹ. Nijọ ti idajọ Ọlọrun ba de ni tootọ, oju gbogbo wa ni yoo ṣe.

(39)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.