Osu meji ni Tobi to ji ẹrọ akọrin yoo se lewon

Spread the love

Ọmọkunrin ẹni ọdun mọkandinlogun kan, Tobi Ayinde, lo ti dero ọgba ẹwọn l’Abẹokuta bayii, nigba to ji ẹrọ akọrin Home Theatre ati amohun-dun-gbẹmu ( Speaker), ti adajọ si paṣẹ pe ko lọọ ṣẹwọn oṣu meji gẹgẹ bii iya ẹṣẹ rẹ.
Ọjọ Ẹti to kọja yii ni wọn foju Tobi han ni kootu Majisireeti to wa n’Iṣabọ, l’Abẹokuta. Agbefọba, Idowu Ogunlẹyẹ, si ṣalaye fun kootu pe ọgbọnjọ, oṣu kẹwaa, ni ọmọdekunrin yii ji awọn ẹrọ meji yii ninu ile kan laduugbo Olomoore, l’Abẹokuta.
O ni bo ti ko awọn eelo to n kọrin naa dani lọtun-un-losi lo fu awọn agbaagba adugbo yii lara ti wọn fi da a duro pe nibo lo ti ri ohun to ko dani. Ai le ṣalaye ibi to ti ri i fawọn ti wọn ko o loju lo jẹ ki wọn mu Tobi pẹlu ẹru to ko dani ọhun, wọn si gbe e lọ si teṣan ọlọpaa Lafẹnwa, nibi to ti jẹwọ pe oun ji awọn ẹrọ naa ni.
Nigba to n ṣalaye ara ẹ ni kootu, ọmọkunrin naa jẹwọ pe loootọ loun ji awọn nnkan eelo ile yii. O ni ṣugbọn ki adajọ ṣiju aanu wo oun, oun ko ni i se bẹẹ mọ.
Ẹsun ole jija ti wọn mu Tobi fun yii tako abala irinwo ati ọgbọn, (430), ninu ofin ipinlẹ Ogun ti wọn ṣe lọdun 2006, ijiya si wa fun un.
Adajọ T.O Ọbasanjọ paṣẹ pe ki ọdaran naa lọ si ẹwọn oṣu meji, ko fi aaye owo itanran silẹ rara, o ni dandan ni ko ṣẹwọn naa, ko le jẹ ẹkọ fun un ati fawọn mi-in ti wọn fẹran ki wọn maa fọle onile.

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.