Osinbajo ṣepade pẹlu awọn ori-ade l’Ọṣun lori eto aabo

Spread the love

Florence Babaṣọla

Lati le wa ojutuu si ọrọ ijinigbe ati ipaniyan to ti di ojoojumọ bii ẹkun apọkọjẹ niha Iwọ-Oorun Guusu orileede yii, Igbakeji Aarẹilẹ wa, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajọ, ti ṣepade bonkẹlẹ pẹlu awọn lọbalọba nipinlẹ Ọṣun lọsẹ to kọja.

Bo tilẹ jẹ pe wọn ko faaye gba awọn oniroyin nibi ijiroro naa, eleyii to waye nilegbee gomina ipinlẹ Ọṣun niluu Oṣogbo, Ọṣinbajo ba awọn oniroyin sọrọ lẹyin ipade yii nipa ohun ti wọn jiroro le lori.

O ṣalaye pe awọn ti kọkọ ṣepade pẹlu awọn gomina ilẹ Yoruba lati le mọ ero ọkan wọn lori ọna abayọ si ọrọ eto aabo, ijọba waa pinnu pe o di dandan kipade waye pẹlu awọn lọba-lọba nitori awọn gan-an ni wọn wa lẹsẹkuku. O ni ijọba apapọ orileede yii ko sun, bẹẹ ni wọn ko wo lori ọna ti eto aabo to daju yoo fi wa fun gbogbo awọn araalu, idi si niyẹn ti Aarẹ fi ran oun lati maa ṣepade kaakiri lori ọna abayọ.

Igbakeji Aarẹ ni lara awọn nnkan tijọba apapọ n fọkan si gẹgẹ bii ọna abayọ ni idasilẹ awọn ọlọpaa agbegbe, nibi ti awọn to mọ nipa agbegbe kọọkan yoo ti maa ṣe ẹṣọ nibẹ.

O ni ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa lorileede yii ti gba aṣẹ ijọba lati gbe igbesẹ naa, iyẹn ni gbigba awọn ọmọ ilu kọọkan si iṣẹ ọlọpaa, to si jẹ pe agbegbe ti wọn ti wa gan-an ni wọn yoo pin wọn si. Nigba ati wọn ti wọn mọ ẹnikọọkan lagbegbe wọn, ti wọn si gbọ ede ara wọn, ti wọn mọ apade ati alude wiwọle ati jijade ninu ilu kọọkan ba n ṣiṣẹ aabo nibẹ, yoo ṣoro ki ajeji to wọle ṣiṣẹ ibi. O waa rọ awọn lọbalọba nipinlẹ Ọṣun lati fọwọsowọpọ pẹlu ijọba lori eto aabo.

Ninu ọrọ tirẹ, gomina ipinlẹ Ọṣun, Alhaji Gboyega Oyetọla, ẹni ti igbakeji rẹ, Benedict Alabi ṣoju fun dupẹ lọwọ Aarẹ Buhari fun akitiyan rẹ lori ifọkanbalẹ awọn araalu. 

O ni ipinlẹ alaafia nipinlẹ Ọṣun tẹlẹ ko too di pe awọn ọdaran ajikusawa ya wọbẹ, to si da bii ẹni pe gbogbo nnkan dojuru bii ẹsẹ telọ.

Ọọni ti Ileefẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, ẹni to ko awọn ọba bii ọgọrun-un sodi lọ sibi ipade naa, sọ pe awọn ti ṣetan lati ṣiṣẹ pọ pẹlu ijọba apapọ lati le ri i pe aabo to nipọn pada saarin ilu.

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.