Oshiomhole ati awọn aṣaaju ẹgbẹ oṣiṣẹ ni wọn le mi kuro ninu ẹgbẹ oṣelu Labour-Mimiko

Spread the love

Ki i ṣe iroyin  mọ pe gomina ana nipinlẹ Ondo, Dokita Oluṣẹgun Mimiko, ti kuro ninu ẹgbẹ oṣelu Labour, ọkunrin naa ti lọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu mi-in to pe ni Zenith Labour (Zenith Labour Party, ZLP).

Akọwe iroyin gomina ana ọhun, Ẹni Akinsọla, ninu alaye to ṣe fun wa lori idi ti ọga oun fi kuro ninu Ẹgbẹ Labour lọ sinu ẹgbẹ tuntun mi-in, sọ pe ẹgbẹ naa ti kuro lori ilana ti wọn fi pilẹ rẹ ni nnkan bii ọdun diẹ sẹyin.

Ẹgbẹ oselu Labour lo sọ pe o ti yipada, to si ti di ẹgbẹ oṣelu eyi ti awọn ọmọ ẹgbẹ APC nipasẹ Alaga wọn, Adams Oshiomọlẹ, n dari. Mimiko fẹsun kan Oshiomhole pe ṣe lo n lo ipo rẹ gẹgẹ bii aarẹ

ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ tẹlẹ ri lorilẹ-ede yii pẹlu ifọwọsowọpọ awọn to jẹ adari oṣiṣẹ lọwọlọwọ lati ja Ẹgbẹ Labour gba mọ awọn oludasilẹ ẹgbẹ naa lọwọ. Mimiko ni lati ọjọ ti oun ti fifẹ han lati dije fun ipo aarẹ ni inu Oshiomhole ko ti dun si oun. O ni oun ko fẹ iru iriri ti oun ni lọdun 2016 ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, nibi ti ẹgbẹ yii ko ti fun oun laaye lati yan ẹni ti yoo gba ipo lọwọ oun.

Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtala, oṣu kẹfa, ọdun yii, ni Mimiko kọwe si awọn aṣaaju ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ondo, pe oun ko ba wọn ṣe ẹgbẹ naa mọ. Ọjọ keji rẹ ti i ṣe Ọjọbọ, Tọsidee, lo kede fun gbogbo eeyan pe oun ti pada sinu Ẹgbẹ Labour, labẹ asia  ẹgbẹ oṣelu ti wọn fi dibo yan oun gẹgẹ bii gomina lọdun 2007. Ṣugbọn to ti tun kuro ninu ẹgbẹ ọhun bayii.

(19)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.