Oshiomhole ṣa fẹẹ ju Ọbasanjọ sẹwọn ṣaa!

Spread the love

Ọrọ kan naa ti awọn alaṣẹ, tabi awọn ti wọn lẹnu ninu ijọba yii maa n sọ to n bi ọpọ eeyan ninu naa ni ki wọn ma gba pe awọn paapaa kuna ninu awọn ohun ti awọn n ṣe. Ọpọlọpọ ileri ti ẹgbẹ wọn ati awọn ti wọn n ṣejọba yii ṣe fawọn araalu ni wọn ko mu ṣẹ, ọpọ ohun ti wọn ni awọn yoo ṣe ni wọn ko ranti lati ṣe mọ, bẹẹ wọn si fẹẹ wọle ibo lẹẹkeji. Ohun ti wọn waa mu bii ọrọ ni lati maa bu awọn ẹlomiiran fun aikoju-oṣuwọn tiwọn. Bi wọn ba ni wọn ko san owo-oṣu, wọn yoo ni Jonathan lo kowo jẹ, bi wọn ba ni awọn kan n kowo jẹ ninu ijọba tiwọn yii naa, wọn yoo ni awọn Jonathan ni wọn fi jọ, bi wọn ba si ni ko si ina, wọn yoo ni Ọbasanjọ to ti gbejọba silẹ lati ọdun mejila sẹyin lo fa a ti awọn ko fi rina. Ṣugbọn ewo ni APC funra wọn fẹẹ ṣe, ohun ti araalu fẹẹ mọ niyẹn. Igba ti wọn tilẹ waa yan Adams Oshiomhole si ipo alaga yii, nnkan tilẹ waa buru si i. O da bii pe ko si ohun ti yoo mu inu ọkunrin yii dun ju ko wa ọgba ẹwọn kan ju Ọbasanjọ si lọ. Ọsẹ to kọja ni Oshiomhole tun jade pe bi awọn ba bẹrẹ si i wadii idi ti ina ko fi tan daadaa ni Naijiria, ẹwọn lawọn yoo ju Ọbasanjọ si. Nigba ti ijọba ba fi odidi ọdun mẹrin dari ilu, ti wọn ko ri ẹyọ kan yanju ninu gbogbo iṣoro to wa nilẹ, to jẹ awọn ijọba to ti lọ ni wọn n bu pe wọn ko jẹ ki awọn le yanju ẹ, o yẹ ki araalu mọ pe ijọba bẹẹ ko kun fun awọn eeyan ti wọn mọ ohun ti wọn n ṣe. Tabi awọn ko ṣe iwadii kankan, wọn ko kawe kankan ki wọn too sọ pe awọn fẹẹ ṣejọba orilẹ-ede yii ni. Bawo ni eeyan yoo ṣe fẹẹ gbajọba ibi kan ti ko ti ni i wadii ohun to n lọ nibẹ tẹlẹ, to jẹ bo ba gbajọba tan ni yoo maa wa awawi kiri. Eyi ti a gbọ nipa Ọbasanjọ lẹnu Oshiomhole yii to, ki awọn naa jokoo ki wọn ṣiṣẹ bii iṣẹ, ki wọn mu idẹrun ba araalu, ohun tawọn ọmọ Naijiria n fẹ niyẹn, ki i ṣe ariwo lasan tabi ti redio asọrọmagbesi.

 

(54)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.