Orukọ Akinlade ti ko jade ninu iwe INEC, wọn ni ẹjọ Oshiomhole ni

Spread the love

Ọjọ Ẹti to kọja yii ni iwe orukọ awọn ondije dupo ti ajọ to n ṣeto idibo nilẹ wa, INEC, fọwọ si jade. Ṣugbọn ni ti ipinlẹ Ogun, orukọ Adekunle Akinlade ko si nibẹ, kaka bẹẹ, ti Dapọ Abiọdun lo jade, lawọn eeyan ba ni iṣẹ ọwọ Alaga apapọ APC, Adams Oshimohole, ni.
Bo tilẹ jẹ pe ki i ṣe ayanfẹ Gomina Ibikunle Amosun yii nikan ni orukọ rẹ ko jade, to jẹ ọpọ orukọ awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ yii ti wọn je APC naa ni ajọ INEC ko ri ro rara, sibẹ, ti ondije dupo gomina yii lo fa awuyewuye ju, nigba to jẹ alatako Akinlade, iyẹn Dapọ Abiọdun, ati igbakeji ẹ, Bọde Mustapha, ni ajọ yii gbe jade gẹgẹ bii ondije dupo lọdun to n bọ.
Bakan naa lọmọ ṣori nile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun, ninu awọn ọmọ ile mẹrindinlọgbọn to wa nibẹ, awọn mẹta pere ninu APC lorukọ wọn jade latọdọ INEC, awọn naa si ni Ọlakunle Oluọmọ to n ṣoju ẹkun Ifọ kin-in-ni, Dare Kadiri, to n ṣoju Ariwa Ijẹbu ati Israeal Jọlaosho to n ṣoju Ewekoro.
Ko sohun to fa didi ẹbi ọrọ yii ru alaga apapọ APC bi ko ṣe bi aarin ọkunrin naa pẹlu Amosun ko ṣe gun rege. To jẹ ẹyin Dapọ Abiọdun ni Oshiomhole wa, to kọyin si Amosun ati Akinlade tiyẹn fa kalẹ gẹgẹ bii ẹni ti yoo gba iṣakoso ipinlẹ Ogun lọwọ oun ni 2019.
Ṣugbọn Adams Oshiomhole ti ki i dakẹ siru ẹsun bayii tẹlẹ ko lẹnu ọrọ kan mọ bayii, idaamu to n koju ẹ lori owo abẹtẹlẹ ti wọn lo gba lasiko ibo abẹle, ati bi wọn ṣe ni ko fipo alaga naa silẹ lọkunrin naa n ba yi lasiko yii, koda, wọn n tudii ẹ wo lọwọ lori bo ṣe ṣowo ipinlẹ Edo fọdun mẹjọ to fi ṣe gomina ibẹ.
Eyi naa lo fa a to fi yẹra kuro ni Naijiria lọsẹ to kọja, to gba oke okun lọ.
Bo si tilẹ jẹ pe Amosun ti sọrọ ni tiẹ pe oun ko mọ nnkan kan nipa idaamu Oshiomhole, ti gomina naa ṣalaye pe oun ko lọwọ ninu bi ileeṣẹ Ọtẹlẹmuye ṣe n pe e lati ṣalaye ara ẹ, sibẹ, awọn to loye ọrọ naa ko yee sọ pe igbimọ awọn gomina ti alaga yii n ba fa wahala lori ẹni ti wọn fa kalẹ lo wa nidii iṣoro rẹ, eyi ti gomina ipinlẹ Ogun ati ti Imo, Rochas Okorocha, wa ninu wọn.
Bi ifa INEC ko ṣe fọre fun Akinlade naa ni ko bimọ ire fun ọkunrin oloṣelu ti wọn n pe ni Ọladipupọ Adebutu naa. Gbogbo inawo nara to ṣe lori ibo abẹle ko mu nnkan kan jade rara, nitori INEC ko gba a wọle, kaka bẹẹ, alatako rẹ ninu PDP kan naa, iyẹn Adeleke Shittu lorukọ ẹ jade bii ẹni ti yoo ṣoju PDP nipo gomina Ogun lọdun to n bọ, bẹẹ ni wọn si fi orukọ Reuben Abati ti yoo ṣe igbakeji ẹ ti i lẹgbẹẹ.
Ṣe ija ti wa nilẹ tẹlẹ labala tawọn Adebutu ati Kashamu, ile-ẹjọ ni Adeleke Shittu to jẹ ọmọ ẹyin Buruji Kashamu lawọn faramọ. Ṣugbọn orukọ Shittu to tun jade yii tubọ mu ọrọ naa gbona janjan lọkan Ladi, ọmọ Baba Ijẹbu ni.
Ni ti ẹgbẹ Labour, orukọ ondije dupo gomina ati tawọn ọmọ ile igbimọ aṣofin wọn ko ti i jade rara lasiko ti a n kọ iroyin yii. Ohun ti a gbọ ni pe o ṣee ṣe ko jẹ nitori ija agba to n lọ ninu ẹgbẹ naa nipinlẹ yii, ti ko jẹ ki ẹnu wọn ko lori ondije kan lo fa a ti INEC ko ṣe ti i gbe orukọ tiwọn naa jade.
O kere tan, ẹgbẹ oṣelu bii mọkandilogoji ni ajọ INEC ti fi orukọ awọn ondije dupo wọn sita bayii, ti awọn mi-in yoo si tun maa jade si i bi wọn ba ṣe n pari eto lori wọn. Diẹ ninu awọn torukọ awọn ondije wọn ti jade nipinlẹ Ogun ni: Action Democratic Party (ADP), ti abẹnugan ile igbimọ aṣoju nigba kan, Dimeji Bankọle, ti fẹẹ dupo gomina ipinlẹ Ogun.
Ọmọba Gboyega Nasir Isiaka lorukọ ẹ jade lati dupo yii kan naa ninu ADC nipinlẹ Ogun. Oloye Tọpẹ Tokọya ni INEC fọwọ si lati dupo gomina ninu ẹgbẹ ACCORD, nipinlẹ yii, bẹẹ ni ti Rotimi Paṣẹda jade ninu SDP lati dupo gomina Ogun lọdun to n bọ.
Awọn ẹgbẹ mi-in ti wọn tun foju han ni KOWA, Zenith Labour Party, Unity Party, PDC, UPN, APM, ID, ZLP, AGA, AA ati bẹẹ bẹẹ lọ.

(3)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.