Orooru lọkọ mi maa n difa, o tun ṣẹbọ ninu yara, mi o fẹ mọ-Bisi

Spread the love

Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja, ni Abilekọ Bisi Majẹkodunmi gba kootu kọkọ-kọkọ to wa ni Agege lọ, o loun fẹẹ kọ ọkọ oun, Ismail Majẹkodunmi.

Ẹsun mẹta ni obinrin ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn naa ka si ọko rẹ lẹsẹ. O ni ọkunrin naa ko wulo, ika ni, bẹẹ lo si tun fẹẹ pin oun lẹmii.

Obinrin naa ni ọdun meje sẹyin lawọn ti fẹra awọn, bẹẹ ọmọ mẹta ni Ọlọrun fi ta awọn lọrẹ. Gẹgẹ bi abilekọ to n ṣiṣẹ telọ naa ṣe ṣalaye, o sọ pe ọdun mẹwaa sẹyin loun ti mọ ọkọ oun, ṣugbọn lojiji lo yiwa pada, to si bẹrẹ si i lu oun bii bara.

O ni loru ọjọ kan lo ṣadeede gbe ọpẹlẹ Ifa wọle, o loun fẹẹ maa difa, bẹẹ ẹlẹsin Kristẹni ni lasiko toun fẹ ẹ, oun ko mọgba to tun di babalawo. Bisi ṣalaye pe oru ọjọ kan ni Ismail gbe ọpẹlẹ Ifa janlẹ, to n difa. Oorun ẹbọ to n sun lọjọ naa lo ji oun silẹ toun fi beere lọwọ rẹ pe ki lo n ṣe lọganjọ oru.

Iya ọlọmọ mẹta naa ni dipo ki ọkọ oun ṣalaye ọrọ foun, niṣe lo lu oun bii ejo aijẹ. Bisi sọ pe, ‘ọrọ ija ojoojumọ naa ti su awọn ti a jọ n gbele, mi o si fẹ ki ọkọ mi lu mi pa, idi niyi ti mo fi wa si kootu, ki ẹ tu wa ka, ki kaluku le maa gbe ni alaafia. Nibi ti ọrọ wa de, Ismail tun ṣọ fun mi pe mi o kawe, oun ko si le ba ẹni ti ko kawe gbele. Gbogbo eyi ni ọkan mi ko gba mọ ti mo fi fẹ ki kaluku maa gbe lọtoọtọ.’

Adajọ beere boya Ismail kawe, obinrin naa ni iwe mẹwaa loun mọ pe o ka.

Igbimọ idajọ naa, eyi ti Abilekọ Patricia Adeyanju jẹ alaga wọn, gba Bisi nimọran ko ṣi ṣe suuru nile ọkọ rẹ nitori awọn ọmọ to ti wa laarin wọn. O ni awọn maa fiwe ipẹjọ ranṣẹ si Ismail pe o gbọdọ yọju si kootu, awọn yoo si wo boya awọn le ba wọn pari ọrọ naa.

Ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kin-in-ni, ọdun to n bọ, lo sun igbẹjọ wọn si.

 

(10)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.