Ọrọ ti Akeredolu sọ yẹn naa ko daa jare

Spread the love

Ko si ẹni to n jẹ ki awọn ẹya mi-in ti wọn wa ninu ẹgbẹ APC ri Aṣiwaju Tinubu fin bi ko jẹ awọn eeyan tiwa funra wọn. Tinubu le ni iwa tirẹ lọwọ o, ṣe gbogbo oloṣelu lo ni aburu tiwọn, ṣugbọn eyi ti ko dara ni ki eeyan jẹ epo ẹni, ko jẹ ata ẹni, ko si tun pẹlu awọn ẹni to n sọrọ ẹni lai daa. Rotimi Akeredolu le maa binu nitori pe boya Tinubu ko duro ti i nigba to fẹẹ du ipo gomina, ṣugbọn oun ti di gomina, o si ti yẹ ki ija gbogbo ati ikunsinu gbogbo pari. Loootọ lawọn eeyan naa n ri Buhari gẹgẹ bii aṣaaju wọn bayii, ti wọn si n lẹdi apo pọ pẹlu awọn oloṣelu ilẹ Hausa lati fabuku kan Tinubu, nigba to ba ya, iru abuku bẹẹ  naa yoo kan awọn naa, ohun ti Yoruba ko si ṣe nilọsiwaju kan ree, nigba ti ko si iṣọkan gidi kan laarin awọn oloṣelu wa. Akeredolu fi Tinubu ṣe yẹyẹ, o sọko ọrọ ranṣẹ si i lọjọ to n ba  wọn ṣe ayẹyẹ ileeṣẹ Adaba Radio nibẹ, o ni ki lo de ti awọn to n dari ileeṣẹ naa ko ṣe le pe ọga wọn ko waa ṣe ọna to de ileeṣẹ wọn fun wọn. Akeredolu mọ pe ọna to de ileeṣẹ Adaba Radio yii ko dara, Akurẹ si ni ọna yii wa, ki i ṣe Eko, awọn to n gbe Akurẹ ni wọn ṣiṣẹ ni ileeṣẹ yii, bi wọn yoo ba si sanwo ori wọn, ibẹ ni wọn yoo san an si. Yatọ si eyi, o gbagbe pawọn eeyan wọn ni wọn n gbe adugbo naa, ojuṣe Akeredolu ati ijọba rẹ si ni lati ṣe ọna fun wọn. Bi ijọba ko ba ti i lowo, to ba sọ fawọn eeyan pe oun ko ti i lowo lati ṣe e ki wọn ma binu, iyẹn ṣee gbọ. Koda bo ba sọ pe awọn yoo ṣe ọna naa nigba kan, to si fọkan awọn yẹn balẹ, ọrọ rẹ yoo ye ẹni gbogbo. Bo ba si ṣe pe o fẹ owo lọwọ Tinubu loootọ ni, o le ran ọga agba ileeṣẹ naa si i ni bonkẹlẹ, ki i ṣe ko waa duro ni gbangba, ko maa fi Tinubu ṣe yẹyẹ, ko ni o yẹ ko waa ṣe ọna ileeṣẹ wọn, nigba to jẹ oun lo ni redio naa. Awọn nnkan kan wa ti ko dara, awọn oṣelu kan si wa ti a ko gbọdọ maa ṣe. Eleyii ti Rotimi Akeredolu ṣe yii ko daa, bẹẹ ni ko ma gbagbe pe bi ogun ba jẹ lọ, ọgbọn n jẹ bọ lẹyin o.

 

(31)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.