Ọrọ ogun Sikiru Ayinde Barister da wahala silẹ laarin awọn ọmọ *Wọn ni Samson Balogun fẹẹ ta ile baba naa l’Ọkọta lati fi ṣe oṣelu

Spread the love

 

Lẹyin ọdun mẹjọ ti agba ọjẹ olorin nni, Alhaji Sikiru Ayinde Barister, pa ipo da, wahala ti n bẹ silẹ laarin awọn ọmọ ti oloogbe naa fi saye lọ nitori awọn ogun rẹ, ọpọlọpọ wọn lo si ti kọyin sira wọn bayii. Ọkan lara awọn ọmọ bibi oloogbe naa ta a foruko bo laṣiiri to ba akọroyin wa sọrọ lopin ọsẹ to kọja sọ pe latigba ti baba naa ti ku ni nnkan ko ti rọgbọ fawọn, lati gbe igbe aye irọrun ati sisan owo nileewe fawọn ti jẹ ogun nla bayii nitori pe awọn perete kan ti wọn jẹ ẹgbọn fawọn ninu awọn ọmọ ti baba awọn fi silẹ lo jokoo lori gbogbo ohun to yẹ ko jẹ ẹtọ gbogbo mọlẹbi.

‘‘Ọmọ bibi Sikiru Ayinde Barrister ni mi, ṣugbọn ṣugbọn teeyan ba ri mi ko le mọ pe iru mọlẹbi bẹẹ ni mo ti jade, nitori nnkan ko rọgbọ rara lati bii ọdun mẹjọ ti baba ti jade laye, koda bii igba ta a n gbe ogun ti ara wa laarin awa ọmọ ni. Awọn eeyan bii mẹta si mẹrin lo fẹẹ maa da jẹ ohun to tọ si gbogbo awa ọmọ marundinlogoji, eyi lo si n da wahala silẹ laarin wa. A ṣi ni awọn aburo to nilo iranlọwọ lẹnu ẹkọ wọn, ṣugbọn awọn to jẹ ẹgbọn ko ya si wọn, koda, igba mi-in, wọn maa n lọọ ba awọn eeyan lati fi awọn aburo wọn to nilo iranlọwọ yii parọ gba owo.‘‘

Onitọhun ṣalaye pe latigba ti Oloogbe Barrister ti jade laye lọjọ kẹrindinlogun, oṣu kejila, ọdun 2010, awọn ẹgbọn oun mẹrin kan; Rasaq, Sulieman, Samson ati Mọruff nikan lo n jẹ gaba lori gbogbo ile ati owo to n wọle sapo mọlẹbi atawọn nnkan mi-in to jẹ ẹtọ awọn ọmọ pelu awọn iyawo mẹrindinlogun ti baba fi saye lọ.

‘‘Bii awọn rẹkọọdu dadi (Master Tape) tawọn ẹgbọn lọọ ko fun Buhari Ọlọtọ, tiyẹn si ṣeleri lori saare oloogbe naa pe oun yoo ṣe ohun to ba tọ lori awọn rẹkọọdu naa, gbogbo ohun to ba si jẹ ẹtọ mọlẹbi yoo maa fi nawọ si wa. Ṣugbọn awọn owo kan to wa nikaawọ rẹ, ko ko o kalẹ, o loun n duro de awọn ọmọ to wa loke okun atawọn iyawo lati pejọ koun too ṣe bẹẹ, eyi ko si le ṣee ṣe, nitori pe ko sẹni to wa loke-okun to maa tori owo ti ko to nnkan maa bọ sorilẹ-ede Naijiria. Titi di bi mo ṣe n sọ yii, a o gbọ nnkan kan nipa gbogbo owo dadi, laarin awọn ẹgbọn yẹn nikan lọrọ naa wa, ṣe ni wọn sọ awa ọmọ to ku sinu okunkun.

‘’Gbogbo wa mọ pe Lateef Alagbada lo n ba baba mojuto gbogbo rẹkọọdu wọn nigba ti wọn wa laye, awọn ẹgbọn yii lo kọju ija si Alagbada pe ko fẹẹ san owo fawọn ati bẹẹ lọ. Lẹyin eyi ni Alagbada san miliọnu mẹẹẹdogun naira sinu akanti mọlẹbi, ṣugbọn awọn meji to jẹ ẹgbọn lo lẹtọ lati gba owo jade ninu akanti naa.’’

Nigba ti wọn lawọn ẹgbọn yii gba owo wọn, ko jẹ kawọn aburo wọn mọ si i, wọn gbe eto kan kalẹ lọdun 2015 ti wọn yoo maa fi ṣeranti oloogbe naa bii iru eyi ti wọn maa n ṣe fun Oloogbe Fẹla Anikulapo Kuti ti wọn n pe ni ‘Felabration’, ṣugbọn ‘Barribration’ lawọn yoo maa pe tiwọn. Nigba to di ọjọ ti eto naa waye ninu ọgba LTV8 ni Ikeja, niluu Eko, ọpọlọpọ awọn olorin ti wọn fiwe pe sibẹ ko yọju, ṣe ni awọn aga sofo lọ lọjọ naa. Lẹyin eto naa ni wọn sọ pe awọn ti na gbogbo miliọnu mẹẹẹdogun ti Alagbada san tan.

Lati ọdun to koja ni wọn ti gba gbogbo rẹkọọdu oloogbe naa lọwọ Alagbada, wọn si gbe e fun ẹlomin torukọ rẹ n jẹ Ademọla. Iyẹn san miliọnu mẹrin naira fun mọlẹbi, awọn ẹbi ba ni ki wọn pin owo naa, wọn si pe ipade mọlẹbi. Nibi ipade naa ni Sulaiman ti sọ pe ninu owo naa, wọn maa tun ile oloogbe naa to wa niluu Ibadan ṣe, ile ọhun si ni wọn sọ pe miliọnu mẹrin ko le pari rẹ nitori pe ile nla ni, ibẹ ni oloogbe naa n kọ lọwọ lati ko lọ leyin to ba feyinti lẹnu iṣẹ orin ko too di pe iku pa oju rẹ de lai ro tẹlẹ. Bii aafin ni wọn pe ile janjanran naa. Ibi ti wahala ti bẹ silẹ niyẹn ti ipade naa si daru, titi di akoko yii, a ko gbọ nnkan kan nipa miliọnu mẹrin naira naa lati inu oṣu kẹwaa, ọdun 2017, tipade mọlẹbi ti waye.

Onitọhun tun fẹsun kan awọn ẹgbọn rẹ pe wọn tun n gbiyanju lati ta ile kan to wa ni Ọkọta ti wọn si n parọ fun mọlẹbi pe ijọba ipinlẹ Eko fẹẹ gba ile naa. Ọkan lara awọn ọmọ ti wọn pe orukọ rẹ ni Samson Balogun ti wọn lo fẹẹ dupo ile-igbimọ aṣoju-sofin nipinlẹ Ọyọ ni wọn lo wa nidii ẹ.   Lasiko ti wọn fẹẹ ta ile Ọkọta yẹn ni aṣiri tu nigba ti ẹni to fẹẹ ra a sọ pe oun ni lati ri awọn mọlẹbi, ki wọn le jẹrii pe oun ni wọn ta ile naa fun. Nibi ti ọrọ le de, wọn ni Ọba Isọlọ ba wọn da si i nigba naa. “Gbogbo awọn mọto dadi titi di akoko yii, a o mọ ibi ti wọn wọlẹ si, a o ri wọn mọ. Awọn eeyan yẹn ti ba ilẹ jẹ jinna, aimọye owo ni wọn ti gba lọwọ ijọba ta a gbọ si i.’’

Nigba ti akọroyin wa ba ọkan lara awọn ti wọn fẹsun kan, Ọgbẹni Sulieman, sọrọ lori foonu, o ni awọn eeyan kan lo kan fẹẹ maa ba orukọ ẹbi jẹ ti wọn fẹẹ maa da wahala silẹ. O ni loootọ lawọn fẹẹ ta ile oloogbe naa to wa ni Ọkọta nitori pe o ti jona, awọn mọlẹbi ko dẹ ṣetan lati tun un ṣẹ. Ati pe ile ọhun lawọn ọdaran n lo gẹgẹ bii ibuba wọn, eleyii si le tabuku ba orukọ oloogbe naa. O ni boun ṣe n sọrọ yii, ijọba ipinlẹ Eko ti wo geeti to wọnu ọgba ile naa nitori pe o bọ si abẹ awọn waya-ina, koda, gbogbo mọlẹbi lo ṣepade, ti wọn si panupọ lati ta ile naa ki wọn le fi owo ti wọn ba ri nibẹ tun ile to wa niluu Ibadan ṣe. O ni awọn to fẹẹ maa gbọ awuyewuye bi wọn ṣe n gbọ nile Oloogbe Mọshood Abiọla ati bẹẹ lọ lo n sọ isọkusọ kiri. ‘‘Ki n ma purọ fun yin, ṣe ẹ ri ọrọ mọlẹbi wa yii, ọpọlọpọ eeyan wa to dide lẹyin iku baba ti wọn si n waa ba wa pe ọmọ bibi Sikiru Ayinde Barrister ni wọn. Awa gan-an o mọ gbogbo awọn ọmọ tan, idi niyii ti Buhari Ọlọtọ fi sọ pe ka lọọ ṣe ayẹwo-ẹjẹ, DNA, ka fi le mọ awọn to jẹ ojulowo ọmọ loootọ, ṣugbọn ṣe ni awọn kan to n pe ara wọn ni ọmọ Barrister sa lọ nigba ti wọn gbọ ọrọ DNA. Emi kọ ni akọbi, Bọọda Rasaq ni akọbi, mi o dẹ lero pe bi a ṣe dagba to yii, ẹnikan maa waa yan ẹlomi-in jẹ. Eelo gan-an ni gbogbo nnkan ta a n sọ yii. Emi gẹgẹ bii ẹnikan, mo niṣẹ gidi lọwọ, mo dẹ tun n ṣowo, aimọye awọn ti mo ti ran lọwọ lapo ara mi.

‘‘Gbogbo awa ọmọ Barrister la kawe yanju, a ni lọọya atawọn eeyan nla. Mi o ro pe awọn eeyan perete kan ni agbara lati lawọn fẹẹ jokoo lori ogun Sikiru Ayinde Barrister, ko le ṣe e ṣe. Bi ẹnikan ba waa jade to bẹrẹ si i sọ pe nitori pe wọn ko ti i pin ogun Barrister, a jẹ pe boya ebi n pa iru ẹni bẹẹ ni tabi boya awọn ẹgbọn rẹ tabi iya rẹ kan lo n ti i. Iru ẹni to n sọ nnkan bẹẹ ko le jẹ aburo mi. Ko si ẹnikan to pin owo kan laarin ara wọn lai jẹ pe awọn mọlẹbi mọ si i. Ero mọlẹbi ni pe ta a ba tun ile to wa niluu Ibadan ṣe, a maa gbe e fun awọn to maa maa lo o lati jẹ ki owo maa wọle. Owo to ba ku, a maa pin in laarin mọlẹbi. Bawo waa ni emi, tabi Mọruff ati Samson yoo ṣe waa jokoo le awọn ogun baba naa.

‘’Ile to wa ni Ọkọta yii lo wa lopopona Lamina Lawal, ṣugbọn ẹni to ba n ti n lọ Lamina Lawal, ile Barrister ni wọn maa n fi n ṣe apejuwe, ko si onimọto tabi ọlọkada ti ko mọbẹ.’’

O ni loootọ lawọn ṣe iranti oloogbe naa lọdun 2015, tawọn si nawo le e lori, ṣugbọn oun ko le sọ pato iye tawọn na le eto naa. O ni ẹni to ba fẹẹ wadii iye tawọn na le lọ sọdọ Ọnarebu Samson Balogun to fẹẹ dupo ile-igbmọ aṣoju-sofin, to jẹ oluṣiro-owo lọ lati beere lọwọ ẹ. O ni awọn pe awọn olori nla nla, ṣugbọn wọn ko wa sibẹ fun idi kan toun ko le sọ, tabi boya wahala kan to ti wa nilẹ tẹlẹ. Ọgbẹni Sulieman sọ pe ko sẹni to le na ninu owo oloogbe naa lai jẹ kawọn ẹbi mọ si i. ‘’Awa ko kabaamọ pe a n gbiyanju lati jẹ ki owo wọle sapo mọlẹbi nipa eto ta a ṣe niranti Sikiru Ayinde Barrister ti ko seso rere, to ba jẹ pe kinni naa yọri si rere ni, mo mọ daju pe iru ẹni to n sọ isọkusọ bẹẹ ko ni i sọ ọ. Gbogbo wa la mọ pe eeyan maa n gbe igbesẹ ni laye, o le yọri si rere tabi ida keji. A fi ẹmi wa wewu nipa gbigbe igbesẹ lati ma jẹ kawọn alagbata (Marketer) maa ṣe ayederu rẹkọọdu baba wa jade, ṣugbọn pẹlu gbogbo akitiyan wa naa, wọn ko gbe oriyin fun wa.’’

(489)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.