Ọrọ awọn APC to pin si meji yii lewu o

Spread the love

 

Gbogbo ẹni to ba fẹran ẹgbẹ oṣelu APC, tabi to ba fẹran ijọba Buhari yii gidigidi, iroyin to jade lọsẹ to kọja yii ki i ṣe iroyin gidi, ẹni to ba si ni agbara kan lati sa, ko tete lo agbara naa, ki ẹgbẹ naa pada si bi wọn ti wa tẹlẹ, ko too di pe ọrọ yoo bọ sori. Awọn kan yoo ni ko ṣoro, wọn yoo ni ko si ohun to ṣe APC, pe awọn ọmọ PDP ti wọn wa ninu ẹgbẹ naa ni wọn lọ, awọn si ti mọ wọn tẹlẹ, APC wa kampe. Awọn yii ti gbagbe pe ko si APC nilẹ yii tẹlẹ, pe igba ti awọn gomina meje ọmọ PDP kan darapọ mọ wọn ni wahala de ba PDP, awọn ni wọn si darapọ mọ awọn ẹgbẹ keekeeke to ku ti wọn fi di APC, ti wọn si le PDP lọ. Iyẹn lawọn APC akoko yii ṣe gbọdọ mura, ki wọn mojuto ẹgbẹ wọn ati ijọba Buhari. Ọrọ ti olori ẹgbẹ naa tuntun n sọ pe ko siṣoro, awọn to lọ yẹn ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ awọn tẹlẹ, oun naa mọ pe isọkusọ ni, o kan n janu lasan, o n fọkan awọn to nifẹẹ ẹgbẹ naa balẹ lori ofurujagado ni. Ki ọrọ too ri bayii, kinni kan ni yoo ti ṣẹlẹ. Ọrọ ọhun ki i ṣe ọrọ Saraki nikan tabi ọrọ Atiku tabi ọrọ Kwankwaso, ọrọ ọpọlọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ naa ti inu wọn ko dun si bi Buhari ti ṣe fun wọn ninu ẹgbẹ yii lẹyin ti wọn ja ija ajadiju lati ri i pe o wọle ijọba ni. Ẹni ti yoo ba tan ara rẹ ni yoo ni kidaa awọn ọmọ PDP lo n binu, ko sẹni ti ko mọ pe inu awọn Baba Bisi Akande ati Aṣiwaju Bọla Tinubu paapaa ko dun, wọn kan n mu un mọra ni. Ọpọ eeyan lo mọ ipa ti aarẹ tẹlẹ, Ọbasanjọ ati Ibarahim Babangida ko lati jẹ ki Buhari wọle, bi gbogbo awọn eeyan yii ba waa kọyin si baba yii loni-in, a jẹ pe nnkan kan wa ninu iwa rẹ to ku diẹ ni, paapaa bo ṣe n ṣe pẹlu awọn aṣaaju ẹgbẹ wọn. Awọn ohun to yẹ ki Oshiomhole ati awọn ti wọn ba fẹran ẹgbẹ naa ja fun ree, ki wọn si dari ọkọ ẹgbẹ yii si ibi to ba dara. Ṣugbọn bi wọn ba jokoo si Abuja nibi ti wọn ti n mu waini, ti wọn n sọ pe ko si nnkan kan, ko si nnkan kan, nigba ti nnkan naa yoo ba gbe wọn mi, wọn ko ni i lagbara lati le ja ajabọ o.

(52)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.