Ori ko Sherifat, ọmọ yunifasiti Ekiti, yọ lọwọ awọn ajinigbe

Spread the love

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Ori  ko akẹkọọ kan, Sherifat Idris, yọ lopin ọsẹ to kọja lẹyin tawọn ajinigbe kan gbe e lagbegbe Atikankan, niluu Ado-Ekiti, ṣugbọn tawọn fijilante gba a silẹ nibi ti wọn fi i pamọ si.

Sherifat, ọmọ ẹka ẹkọ imọ ohun amuṣagbara (Physics) ni Fasiti Ekiti la gbọ pe awọn kan foogun gba, ti wọn si ji i gbe, ṣugbọn ẹlẹyinju-aanu kan to ri wọn ta awọn fijilante lolobo.

Nigba to n sọrọ lẹyin toju ẹ walẹ, ọmobinrin naa ni Ọja Ọba loun lọ lati ra nnkan, lasiko toun si fẹẹ wọ ọkọ ero kekere ti wọn n pe ni Akoto lawọn ọkunrin mẹta kan waa ba oun, ti wọn si fi nnkan gba oun, nnkan toun ranti mọ niyi.

ALAROYE gbọ pe ẹni to ri awọn oniṣẹ ibi naa lo pe awọn fijilante tawọn yẹn si bẹrẹ iṣẹ loju-ẹsẹ, bẹẹ ni wọn ya bo ibi tawọn eeyan naa mu Sherifat pamọ si. Nigba ti iye rẹ ṣi pada lo bu sẹkun nigba ti nnkan to ṣẹlẹ ye e, bẹẹ lawọn fijilante yii ba a ri ọpọlọpọ nnkan ti wọn gba lọwọ ẹ pada.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Akin Ọlọunloni to jẹ adari fijilante nipinlẹ Ekiti ṣalaye pe kawọn too de ibi tawọn ajinigbe naa wa ni wọn ti sa lọ nitori awọn kan ta wọn lolobo lagbegbe Atikankan. O ni awọn ko fi ọrọ naa falẹ rara lo jẹ kawọn ri Sherifat gba pada.

Iwadii ALAROYE fi han pe agbegbe Atikankan yii jẹ ibi tawọn ọdaran pọ si, ti oriṣiiriṣii nnkan si ti n ṣẹlẹ, bẹẹ lo jẹ pe awọn ọlọpaa ati ajọ to n gbogun ti oogun oloro (NDLEA), maa n ri awọn afurasi mu nibẹ daadaa.

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.