Ori ko Bibire Ajapẹ, gbajumọ oloṣelu yọ ninu ijamba mọto

Spread the love

Gbajumọ oloṣelu nipinlẹ Kwara, Alhaji Usman Bibire Ajapẹ, lori ko yọ ninu ijamba mọto to ṣẹlẹ lọna Oke-Oyi, niluu Ilọrin, lọjọ Ẹti, Furaidee ọsẹ to kọja.

Dẹrẹba rẹ la gbọ pe o ba iṣẹlẹ naa lọ bẹẹ lawọn mi-in ti wọn farapa ṣi n gba itọju nileewosan ẹkọṣẹ Fasiti Ilọrin, UITH.

Ọkunrin to figba kan jẹ oluranlọwọ pataki feto fifi opin si iṣẹ ati oṣi (Poverty Alleviation) nipinlẹ Kwara labẹ ijọba Bukọla Saraki lo n lọ Oke-Oyi lọjọ iṣẹlẹ naa.

O ti figba kan ṣe alaga ijọba ibilẹ Ila-Oorun Ilọrin, ti Oke-Oyi jẹ olu ijọba ibilẹ naa.

ALAROYE gbọ pe ọkunrin naa ri awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ ti wọn n ṣọ ọkọ laaarọ ọjọ naa to si paṣẹ fun dẹrẹba rẹ lati duro ko wọn gẹgẹ bo ṣe maa n ṣe.

Nigba ti wọn fi maa rin siwaju diẹ ni mọto naa ya kuro loju ọna to si lọọ wọnu koto nla kan to wa nibi odo Ọyun.

Ọna naa ni ijọba n fẹ loju lati sọ di onibeji bẹrẹ lati agbegbe Sango titi de Oke-Oyi. Nitori iṣẹ to n lọ lọwọ nibẹ koto nla wa lẹgbẹẹ titi to le gbe odidi mọto mi.

Ajapẹ lo tun ti dipo oludamọran pataki Gomina Abdulfatah Ahmed lori ọrọ irinna, o si tun figba kan ṣe oludamọran feto oṣelu.

O ti ba Baba Saraki, Oloogbe Abubakar Oluṣọla Saraki ṣiṣẹ daadaa, ko too di pe o tun tẹsiwaju lati jẹ ọkan lara awọn to n ba Sẹnẹtọ Bukọla Saraki ṣeto oṣelu Kwara.

Oun naa wa nibi ifilọlẹ ipolongo ibo fun igbakeji aarẹ ana, Atiku Abubakar, to waye lọsẹ to kọja.

 

(7)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.