Ori Ade ni kootu! Ọladele wọ Alọba Ilu Ilọba lọ sile-ẹjọ

Spread the love

Ile-ẹjọ giga kan niluu Ileṣa gbalejo Alọba ti ilu Ilọba, Ọba Sanmi Okikiọla lọ sile-ẹjọ. Ko si deede lọ sile-ẹjọ yii naa, Ọlamilekan Ọlanrewaju Ọladele lo wọ ọ lọ sibẹ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja. Ọkunrin naa ni ipo Alọba to wa ko tọ si i rara, oun gan-an loye ọhun tọ si.
Ninu ọrọ Ọladele ni kootu, o ṣalaye pe oun gan-an ni idile ọba fa kalẹ lati jẹ oye Alọba, ṣugbọn oun ko mọ bi Okikiọla ṣe ṣe e to fi di pe wọn mu orukọ ẹ lọ sọdọ ijọba, ti wọn si fi i jẹ oye naa lẹyin oun.
Amọ ninu awijare ọba naa, o ni oun ko da ipo ọba ti oun wa yii gun, awọn afọbajẹ ilu ni wọn mu orukọ oun lọ sile ijọba, ti wọn si fi oun jọba lẹyin ti wọn ti fontẹ lu orukọ oun lọhun-un.
Ṣugbọn agbẹjọro Ọladele, Ọgbẹni Niyi Akintọla, ni ko soootọ ninu ọrọ ọba alade yii, o ni ko si afọbajẹ kankan niluu Ilọba, idile to n jọba lo wa. O mu awọn ẹlẹrii meji wa lati gbe ọrọ rẹ lẹsẹ, ninu awọn ẹlẹrii naa si ni Oloye Odole. Odole ṣalaye pe oun ki i ṣe afọbajẹ ninu ilu naa, oun ko si gbagbọ pe afọbajẹ kan wa nibi kankan lorigun mẹrẹẹrin ilu awọn.
Ẹlẹrii miiran ti wọn tun pe jade nile-ẹjọ ni Ọgbẹni Dayọ Oronigbagbe, oun naa ṣalaye pe ko si afọbajẹ kankan niluu Ilọba, o loun funra oun ki i ṣe afọbajẹ, akọwe ilu Ilọba loun. O ni oun loun fọwọ si lẹta ti awọn araalu Ilọba kọ ranṣẹ si Ọwa Ọbọkun, Ọba Gabriel Adekunle Aromọlaran.
Oronigbagbe ṣalaye pe loootọ loun mọ pe awọn olujẹjọ ati olupẹjọ jọ n du ipo ọba ilu Ilọba ni, amọ ọrọ pe afọbajẹ wa niluu Ilọba yẹn, irọ gbuu ni.
Pẹlu bi agbẹjọro Ọba Sanmi, Ọgbẹni Iraboh, ti ṣe ṣalaye awọn idile afọbajẹ to wa niluu Ilọba, sibẹ, awọn ẹlẹrii mejeeji yii ṣi duro lori ọrọ ti wọn sọ niwaju adajọ lọjọ Wẹsidee to kọja yii.
Agbẹjọro Ọladele, Akintọla, waa rọ ile-ẹjọ pe ki wọn ba awọn sun ẹjọ yii siwaju, tori o ni ẹlẹrii kan to ku ti awọn tun n mu bọ wa sile-ẹjọ lọjọ igbẹjọ mi-in.
Adajọ gbọrọ si agbẹjọro yii lẹnu, o si sun igbẹjọ miiran si ọgbọnjọ, oṣu yii.

(35)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.