Ọrẹ Ọbasanjọ pẹlu Atiku

Spread the love

N ko fẹẹ sọ si ọrọ yii, koda, n ko fẹẹ wi nnkan kan lori ẹ. Lori ipari-ija laarin Ẹgbọn wa, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, ati eeyan wa, Atiku Abubakar, mo ti sọ pe n ko ni i wi kinni kan lori ẹ. Ṣugbọn mi o le feti pa a rẹ nigba ti ẹyin ọrẹ mi ba n sọ pe ẹ fẹ ki n sọrọ fun itọsọna, pe ẹ fẹ ki n wi nnkan kan ki ẹ le mọ iha ti mo kọ si i, ki ẹyin naa le ri i mu lo fi ṣe ohun ti ẹ ba fẹẹ ṣe. Gẹgẹ bi ohun ti mo ti maa n sọ fun yin lati igba pipẹ wa, gbogbo ohun ti mo ba ṣe nibi yii, awọn ọrọ ti mo ba sọ, nitori tiyin ni. Bẹẹ ni ko sohun to maa n dun mọ mi ninu ju ki n ni anfaani lati tọ ẹyin eeyan mi sọna lọ, nitori aṣiṣe ti a n ṣe ti pọ ju, ohun to si n fa awọn aṣiṣe yii ni nigba ti a ko ba ni alaye ọrọ to, tabi ti a ko gbọ ẹkunrẹrẹ ọrọ, tabi ti a ko tilẹ mọ ohun to n lọ. Bi eeyan ba mọ ohun to n lọ, yoo ronu ko too da si i. Ohun ti yoo jẹ ki n sọrọ diẹ niyi.
Akọkọ ni pe ki ẹ mu un kuro lọkan yin pe ohun ti Egbọn ṣe yii, o ṣe e nitori ifẹ Naijiria, tabi nitori ifẹ Yoruba, tabi nitori araalu kankan. Awa ti a mọ Ẹgbọn Ṣẹgun la le sọrọ yii, eyi ko ni i han si awọn ti wọn ba n wo o lokeere. Nigba ti ẹdun ba wa lori igi, yoo maa da ara oriṣiiriṣii, yoo maa re kenda, ṣugbọn ni pọọ to ba ja bọ silẹ, ti ko si ori igi ti yoo gun mọ, bii ọbọ ni yoo maa ṣe, iyẹn ni wọn ṣe n sọ pe ere ka ẹdun mọlẹ, o di ọbọ. Ẹgbọn ko ba Atiku pari ija nitori ẹni kan, tori ara ẹ ni, koda, ki i ṣe nitori Atiku. Koko kan ni, iyẹn ni pe Ẹgbọn fẹ ki Buhari lọ, bi Buhari ko ba lọ, ọrọ naa yoo di itiju soun naa lara, wọn yoo bẹrẹ si sọ pe, “Gbogbo ihalẹ Ọbasanjọ, aṣe ko tilẹ jẹ nnkan kan mọ!” Ohun ti Ẹgbọn o fẹ ko ṣẹlẹ ree, iyẹn lo ṣe dọrẹ Atiku kia. Bo ba jẹ Ẹgbọn ti awa mọ ni o, koda ki Ọlọrun sọkalẹ, ko ni i gbọ ẹbẹ Atiku, yoo ni ẹṣẹ rẹ ti kọja idariji.
Tabi to ba jẹ nigba ti ẹgbọn ni oun fẹẹ da ẹgbẹ oṣelu silẹ, to ba jẹ ẹgbẹ oṣelu naa gbera nilẹ, to lero lẹyin, ti wọn rowo gidi na, ti araalu n sare rọ lọ sinu ẹgbẹ yii, bi Atiku ba de ile rẹ, yoo tilẹkun mọ ọn ni. Ṣugbọn Ẹgbọn ti kọ lẹta si Buhari, o ti leri pe ko ni i jẹ aarẹ Naijiria lọdun to n bọ, ṣugbọn ileri lasan ni, ko sọna ti yoo gba fi mu ileri naa ṣẹ. Ko si ẹgbẹ oṣelu to le ṣe iṣẹ naa, gbogbo ẹgbẹ toun atawọn to n ko kiri da silẹ, ẹgbẹ ti ko lorukọ, ti ko si le mu nnkan kan wale ni wọn, bii igba teeyan n bomi sinu ajadii apẹrẹ ni. Ẹgbọn mọ pe gbogbo ẹgbẹ ti oun ko jọ yii, ko si eyi to le koju awọn APC, tabi ti wọn yoo rẹni fa kalẹ ti yoo koju Buhari. Ọrọ naa si ti di ironu. Bi ẹ ba kiyesi i, ẹ oo ri i pe fun ọpọlọpọ igba, ẹ ko gbohun Ẹgbọn Ṣẹgun, ko si sẹni to mọ ohun to n lọ lọkan rẹ, nigba naa ni Atiku wọle ninu idibo awọn PDP.
Ẹgbọn Ṣẹgun mọ pe nibi ti ọrọ oṣelu Naijiria wa loni-in yii, awọn meji pere ni wọn le jade ti wọn le koju Buhari daadaa: Bọla l’Ekoo, ati Atiku ni. Bi Bọla ba jade to ni Buhari ko ṣe daadaa, oun yoo ba a fa a, idi awọn to yi Buhari ka yo domi, nitori owo ati agbara oṣelu Eko to wa lọwọ Bọla. Ẹni to tun ri bii oun ninu oṣelu Naijiria loni-in, Atiku ni, nitori owo to wa lọwọ oun naa ati agbara oṣelu toun naa ni kaakiri. Bọla lo ti jade to ni ẹyin Buhari loun wa yii, bawo waa ni ileri Ẹgbọn yoo ṣe ṣẹ. Kaka ki ọmọde pa mi layo, ma a ti ojooro bọ ọ ni, iyẹn l’Ẹgbọn ṣe fun gbogbo awọn ti wọn fẹran rẹ yii. Nigba ti ọrọ ipari-ija naa di wahala, ẹni to ba gbọ ọrọ ti ojiṣẹ Ọlọrun, Mathew Kukah, sọ lo le mọ itumọ ohun ti mo n wi yii. Alaye to ṣe yoo fihan pe ki i ṣe ohun toun ro nipa ipari ija yii lo ba nigba to dele Ẹgbọn Ṣẹgun.
Awọn eeyan bẹrẹ si i bu awọn ojiṣẹ Ọlọrun yii pe kin ni wọn n wa nibi ti wọn ti lọọ pari ija, pe bawo ni wọn ṣe dele Ẹgbọn yii, kin ni wọn wa lọ. Ṣugbọn Kukah sọ pe o ti le lọdun mẹfa ti oun ti wa lẹnu ọrọ yii, to jẹ ni gbogbo igba loun n bẹ Ẹgbọn ko dariji Atiku. O ni nibikibi ti oun ba ti pade ẹ loun maa n sọ pe ko jẹ ki oun pepade ẹlẹni-mẹta, ki oun wa nibẹ, ki Atiku ati Ẹgbọn si wa nibẹ, ki wọn si pari ija wọn. Ọbasanjọ ko gba. Afi bi oun ṣe pade ẹ nijọ kan lọsẹ to lọ lọhun-un ti oun tun sọrọ naa to ni ko sọna nibẹ, nigba to si to wakati kan lo pe oun pada pe o daa, ki oun mu Atiku wa, bo ba jẹ o fẹẹ pari ija naa loootọ. Kukah ro pe Atiku nikan ni yoo ba oun lọ sile Ọbasanjọ, afi igba ti Ẹgbọn tun pe e to ni ko sọ fun Atiku pe to ba n bọ, ko mu alaga PDP ati awọn aṣaaju ẹgbẹ naa diẹ dani.
Sibẹ, Kukah ko ti i mọ nnkan kan, afi igba to debẹ to ri i pe Ẹgbọn ti ranṣẹ si Sheikh Gumi funra ẹ pe oun fẹ ko wa nibi ipari-ija oun ati Atiku, bẹẹ lo pe Biṣọọbu Oyedepo, to si pe awọn oloṣelu PDP mi-in si i, wọn si ṣe eto naa bii ẹni pe gbogbo wọn ni wọn wa funra wọn lati waa ba Atiku bẹ Ẹgbọn Ṣẹgun, awọn ojiṣẹ Ọlọrun naa lo si bẹ ẹ titi to fi gbọ. Bẹẹ ọrọ yii ko ri bẹẹ rara. O ti rẹ ija ni. O rẹ ija pata, nitori Ẹgbọn ko tun ri ẹni to le ba oun le Buhari lọ afi Atiku nikan. Iyẹn ki i ṣe pe ohun to ṣẹlẹ naa ko daa o, nitori ẹnikẹni to ba le le Buhari kuro nipo to wa yii, oore lo ṣe fun Naijiria, deede ara temi lo ṣe. Mo ti sọ tẹlẹ pe bi ẹgbẹ APC ba mọ pe awọn yoo wọle ibo lọdun to n bọ, ki wọn bẹ Buhari ko jẹ ki wọn fa ẹlomi-in kalẹ, tabi ki ẹlomi-in jade ninu ẹgbẹ wọn, ki wọn si mu un jade, nitori iwa ti Buhari n hu nile ijọba ni ko jẹ ki ọpọ eeyan fẹ ẹ.
Ọrọ ẹgbẹ oṣelu kọ leleyii, ẹni to ba n ronu lori APC tabi PDP, tọhun yoo kan maa ti inu okunkun bọ sinu okunkun ni. Ẹni ba si n feti si ariwo pe PDP ole, APC lo mọ, tọhun kan n tan ara rẹ jẹ ni. Latigba ti wọn ti bẹrẹ ọrẹ iranu ti wọn ni wọn n ṣe yii ni mo ti sọ fun yin pe ko siyatọ ninu APC ati PDP, mo wi daadaa fun yin lọjọ naa lọhun-un, gbogbo awọn eeyan ti ẹ n fi apa janu nitori wọn lọjọ naa lọhun-un, ti ẹ n sọ pe wọn ti yipada, APC ni wọn yoo ṣe titi ti wọn yoo fi ku, awọn naa ni wọn ti pada sinu PDP ti wọn ti lọ yii o. Bẹẹ ọpọlọpọ ni yoo si tun lọ. Ki lo fa a? Ko sohun to fa a ju pe nnkan kan naa ni wọn ni, ko siyatọ ninu wọn. Ṣugbọn ẹni ti wọn ba fi si ipo olori nikan lo le mu nnkan yatọ, ẹni to ba jẹ olori Naijiria lo ni gbogbo agbara, ibi to ba si dari ọkọ Naijiria si ni motọ naa yoo gba, ati gbogbo awa ero ti a wa ninu ẹ.
Ilọsiwaju ilu, idagbasoke ọrọ-aje, ka gbogun ti iwa ibajẹ atawọn ole, gbogbo eleyii dara nigba ti a ba ni orilẹ-ede kan ni, nigba ti iṣọkan ba wa, ti orilẹ-ede si duro ṣinṣin. Orilẹ-ede Naijiria ko duro ṣinṣin, ko si iṣọkan tabi irẹpọ, iwa ti Buhari si hu nile ijọba laarin ọdun mẹta yii tubọ ba kinni naa jẹ debii pe bo ba lo ọdun mẹrin mi-in loootọ, afaimọ ki Naijiria ma tun ba ara wọn jagun abẹle lẹẹkan si i. Iwa ẹlẹyamẹya Buhari buru, iwa ka gbe ẹya tiwa lori gbogbo ẹya to ku, ki ara ile wa jale, ka ni o fẹẹ lo owo to ji ni, ko paayan, ka ni ko mọ-ọn-mọ, ka gba ipo lọwọ iran mi-in, ka gbe e fọmọ tiwa, ki lo yara pa orilẹ-ede kan run ju bẹẹ lọ! Awọn iwa yii lo kun ọwọ Buhari, bi gbogbo aye si ti pariwo to, ko yipada, iyẹn ni ọpọ eeyan bii emi yii, ṣe n gba a laduura pe ki Ọlọrun fun wa lẹlomi-in, ko too di pe baba yii da ogun abẹle silẹ nilẹ wa.
Nidii eyi, bo tilẹ jẹ pe ohun ti Ẹgbọn Ṣẹgun ṣe, ara ẹ lo ṣe e fun, ko ṣe e nitori awọn ọmọ Naijiria, nitori ki iyi ati apọnle ti oun ni ma ṣe wọmi lojiji lo ṣe pari ija pẹlu Atiku, sibẹ, nigba ti Ọlọrun ba fẹẹ gba ẹda kan la, yoo da ija silẹ laarin awọn ọta rẹ, tabi ko gbe ọkan lara awọn ọta rẹ dide ti yoo ja fun un. Bo ṣe ri gan-an ree o. Tabi ẹyin ko mọ pe bi awọn alagbara Naijiria ba n ṣe ọrẹ ara wọn, iya ni wọn yoo fi jẹ mẹkunnu ilẹ yii pa? Wọn yoo kan maa gba wa ni bọọlu bi wọn ba ti fẹ ni. Ṣugbọn bi Ẹgbọn Ṣẹgun ba di ọta Buhari, yoo fi daa fawa mẹkunnu ni. Eleyii ti Ẹgbọn ṣe yii, o n ṣe tiẹ ni, Ọlọrun lo mọ ohun ti oun yoo ṣe fun gbogbo wa. Eyi to dara ni ka sa maa gbadura fun, ki Ọlọrun funra rẹ gbe ẹni ti yoo ran gbogbo awa mẹkunnu ilẹ yii, ati orilẹ-ede yii lapapọ, lọwọ dide.

(28)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.