Ọpọ eeyan farapa nibi eto idibo abẹle ẹgbe APC l’Akurẹ

Spread the love

Wahala to wa ninu ẹgbẹ APC ipinlẹ Ondo tun bọna mi-in yọ lọjọ Abamẹta, Satide, ọṣẹ to kọja yii, pẹlu bawọn tọọgi oloṣelu kan ṣe kọlu awọn ọmọ ẹgbẹ ọhun nibi ti wọn ti n dibo abẹle, ti pupọ wọn si farapa yannayanna.

 

Latari ede-aiyede to ti wa laarin awọn ọmọ ẹgbẹ naa ṣaaju eto idibo ọhun, ọna meji ọtọọtọ ni wọn pejọ pọ si lati ṣeto idibo naa.

 

Gbọngan nla kan ti wọn n pe ni BTO, eyi to wa lagbegbe gareeji Ileṣa, niluu Akurẹ, lawọn igun kan ninu ẹgbẹ naa ti fẹẹ ṣeto ibo tiwọn, nibi ti aṣofin to n ṣoju awọn eeyan ijọba ibilẹ Ifẹdọrẹ ati Idanre nile igbimọ aṣoju-ṣofin l’Abuja, Ọnọrebu Bamidele Baderinwa, ati Bọla Ilọri to jẹ ọkan ninu awọn kọmiṣanna Arẹgbẹṣọla nipinlẹ Ọṣun, atawọn aṣaaju ẹgbẹ mi-in ba wọn peju pesẹ si.

 

Bẹẹ naa ni Gomina Rotimi Akeredolu atawọn alatilẹyin rẹ ko ara wọn jọ si gbọngan aṣa igbalode (Doomu) to wa loju ọna Igbatoro fun eto idibo abẹle tiwọn lasiko kan naa ti ẹka keji n ṣe tiwọn ni BTO.

 

Bi awọn ọmọ ẹgbẹ ọhun ti wọn ko ara wọn jọ si gbọngan BTO ṣe n mura ati bẹrẹ eto idibo tiwọn ni nnkan bii ago mẹsan-an aarọ ọjọ naa lawọn tọọgi kan ti wọn gbagbọ pe wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ awakọ de si gbọngan ọhun pẹlu ọkọ akero mẹfa, eyi ti wọn kun inu rẹ fọfọ.

 

Awọn tọọgi ọhun ko wulẹ fakoko ṣofo ti wọn fi bẹrẹ si i fi ada ati igi ti wọn ko lọwọ dabira si gbogbo awọn eeyan to wa ninu gbọngan ọhun lara.

 

Ọpọ awọn to wa nibi iṣẹlẹ ọhun ni wọn ṣa ladaa yannayanna, ti wọn si tun lu awọn mi-in. Awọn ẹṣọ alaabo to n ṣọ Ọnọrebu Baderinwa ti wọn tete wọna ati gbe e kuro nibi iṣẹlẹ ọhun lori fi ko o yọ bo tilẹ jẹ pe awọn tọọgi ọhun ṣe e leṣe diẹ, ti wọn si tun fasọ ya mọ ọn lọrun.

 

Lẹyin ti aṣofin yii ti raaye sa mọ wọn lọwọ ni tirẹ ni wọn waa fabọ sori Bọla Ilọri, ẹni ti wọn lu daadaa, ti wọn si tun ṣe leṣe ki wọn too gba a silẹ lọwọ wọn.

 

Gbogbo awọn akọroyin to wa nibi eto ọhun lawọn tọọgi yii fọwọ ba, ti pupọ wọn si tun farapa latari alubami ti wọn lu wọn.

 

Gbogbo gilaasi ferese gbọngan ti wọn lo feto ọhun lawọn tọọgi naa fi okuta run womuwomu, ti wọn si tun fi igi ati ada fọ gbogbo gilaasi ọkọ ti wọn ba ninu gbọngan naa.

 

Lẹyin eyi lawọn ọmọ ẹgbẹ ti wọn kọlu naa tun sa kuro niluu Akurẹ, wọn tun sare ko ara wọn jọ sileewe girama Iroko to wa niluu Ọwẹna, nijọba ibilẹ Ifẹdọrẹ, nibi ti wọn ti pada ṣeto ibo naa, ti wọn si dibo yan Idowu Ọtẹtubi gẹgẹ bii alaga ẹgbẹ APC nipinlẹ Ondo, ti Gani Muhammed si di akọwe ẹgbẹ igun tiwọn.

 

Ibo ẹẹdẹgbẹrun o le ogoji ni Ọtẹtubi ni, nigba ti Ọgbẹni Olubunmi Alọ ti wọn jọ n du ipo naa ni ibo mejidinlogun pere.

 

Ọgbẹni Tolu Babalẹyẹ to ṣaaju igbimọ to ṣeto ibo naa fidi ẹ mulẹ pe wọọrọwọ leto naa lọ, bo tilẹ jẹ pe awọn kan to jẹ ọta ijọba tiwa-n-tiwa ko fẹ ki eto naa waye. Bẹẹ lo ṣapejuwe eto ọhun bii eyi to bofin ẹgbẹ wọn mu nitori gbogbo awọn to yẹ ko waa mojuto eto ibo naa ni wọn peju pesẹ sibẹ.

 

Alaye ti ọmọ ẹgbẹ APC kan to kọ lati darukọ ara rẹ ṣe fun wa lori ohun to n fa rogbodiyan laarin awọn ọmọ ẹgbẹ naa ni pe, awọn ọmọ ẹgbẹ to fẹẹ dije sawọn ipo kan ati omiiran le lẹgbẹrun marun-un, ṣugbọn ti wọn kọ lati ta fọọmu fun wọn.

 

Gbogbo awọn fọọmu ti wọn fi ṣọwọ sipinlẹ Ondo lati Abuja lo sọ pe Gomina Akeredolu atawọn alatilẹyin rẹ gbẹsẹ le, ti gomina ọhun si kọ lati gba kawọn sẹnetọ atawọn aṣofin ẹgbẹ naa fa ẹnikẹni kalẹ gẹgẹ bii oloye ẹgbẹ.

 

Ninu eto idibo kan naa ti Gomina Akeredolu atawọn alatilẹyin rẹ ṣe ni Doomu ni wọn ti dibo yan adele alaga ẹgbẹ naa, Ade Adetimẹhin, gẹgẹ bii ojulowo alaga tuntun, Ọgbẹni Agbabra Ikoto Atili ni igbakeji alaga, nigba ti wọn dibo yan Adesina Alaye gẹgẹ bii akọwe ẹgbẹ fun igun ti Gomina Akeredolu.

 

Aṣoju ti ẹgbẹ APC ran wa lati Abuja, Ọgbẹni Mathew Omegara, jẹ ko di mimọ pe eto ibo naa waye ni ibamu pẹlu alakalẹ ẹgbẹ APC lorilẹ-ede yii. Bakan naa lo dupẹ lọwọ awọn ọmọ ẹgbẹ naa fun ifọwọsowọpọ wọn titi ti wọn fi pari eto ọhun.

 

Gomina Akeredolu toun naa wa nibi eto ọhun ki gbogbo awọn oloye ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan yii ku oriire.

(25)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.